Fáyẹmí pè fún àjọṣepọ̀ àwọn olùdíje fún àṣeyọrí APC l'Ékìtì

Fayemi ati awọ̀n oludije ẹgbẹ oṣelu APC Image copyright Tunji Ariyomo
Àkọlé àwòrán Àwọn olùdíje ti ń fikùlukù lórí ọ̀nà àti mú àṣeyọrí bá ìlàkàkà ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Eto idibo lati yan oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ti pari, o si ṣeeṣe ki eyi fi opin si aawọ to waye laarin awọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa nibẹ nitori bi a ti ṣe n sọrọ yii igbesẹ ti nlọ lati dẹkun dukuu abẹnu nibẹ.

Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti na ọwọ ifẹ si gbogbo awọn oludije yooku pẹlu arọwa pe ki wọn jẹ ki gbogbo ohun to waye lasiko idije fun aṣia ẹgbẹ naa rodo igbagbe lọ ree mumi.

Kókó nípa ìdìbò àti yan olùdíje gómìnà Èkìtì lábẹ́ àṣíá APC

  • Oludije Mẹtalelọgbọn lo dije fun aṣia oludije gomina lẹgbẹ oṣelu APC l'Ekiti.
  • Babafẹmi Ojudu kede pe oun yọwọ ninu idije naa, ṣugbọn orukọ rẹ ṣi papa jade lori iwe awọn oludije.
  • Marundinlọgbọn ninu awọn oludije to dije naa ni awọn to dibo fun wọn ko ju marun lọ.
  • Meji ninu awọn to dije naa ni wọn ti figba kan ri ṣe gomina nipinlẹ Ekiti- Ṣẹgun Oni ati Kayọde Fayẹmi.
  • Ẹgbẹrun meji o le ọọdunrun ati mẹtadinlọgbọn, 2, 327 ni awọn ti wọn ṣe ayẹwo fun lati kopa ninu ibo naa.
  • Kayọde fayẹmi bori pẹlu òjìlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rún lé ẹyọ kan ìbò, 941, nígbà tí Ṣẹgun Oni tó ṣe ipò kejì ni ọ̀rìnlénírinwó lé ẹyọkan ìbò, 481.

Ninu atẹjade kan ti Fayẹmi fi sita lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii olubori fun awọn oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni "igbesẹ akọkọ ni lati gbe igbimọ olubadamọran kalẹ lẹyẹ o ṣọka eleyi ti yoo ko gbogbo awọn oludije mọra".

O sọ síi wi pe "a gbọdọ parapọ ja ija bibọ ajaga aimọkan kuro lọrun awọn eeyan wa, ki a si gba wọn kuro lọwọ aisan ati awọn ohun idena to n de wọn lọna ati de ipo ti o yẹ ki a wa."

Image copyright Olasunkanmi ogunmuko
Àkọlé àwòrán Marundinlọgbọn ninu awọn oludije to dije naa ni awọn to dibo fun wọn ko wọn marun

Fayẹmi ni ohun ti ẹgbẹ oṣelu APC nilo ni iṣọkan awọn eeyan rẹ gbogbo fun aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu naa nibi eto idibo sipo gomina nipinlẹ Ekiti, eleyi ti yoo waye lọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun yii.

O ni "mo gbara le atilẹyin awọn eeyan mi ti a jumọ dije fun iriri, imọ ati ọgbọn inu wọn lọna ati lee gbe ipinlẹ Ekiti soke tente lẹẹkan sii."

Bakannaa la gbọ wi pe ọkan ninu awọn oludije naa, Bimbọ Daramọla, ti ṣeto apejẹ binukonu kan leyi ti yoo fun awọn oludije naa lanfani ati fikuluku lori ẹhonu ati ọna abayọ fun aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu naa nibi idibo sipo gomina to n bọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: