Olópàá Nàíjíríà: A ti rí owó NNPC tí wọ́n kó sílé ìfowópamọ́

Mele Kyari

Oríṣun àwòrán, NNPC

Àkọlé àwòrán,

Mallam Kyari ni ọ̀gá àgbà fún ẹ̀ka tó ń rí sí káràkátà epo rọ̀bì ní àjọ NNPC

Ajọ ọlọpaa ni orilẹ-ede Naijira ni awọn ti ri owó to le ni aadọrinlenirinwo billiọnu dọla to jẹ ti Ajọ Eleto Bẹntirol Lorile-ede Naijiria, NNPC.

Ajọ ọlọpaa ni awọn ile ifowopamọ to wa ní Naijiria ti wọn ko owo naa pamọsi ni awọn ti ṣawari owo naa.

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa, Jimoh Moshood, to fi ọrọ naa lede ni Olu-Ilu Naijria, Abuja fikun un pe awọn tun ti ri owo miran to le ni biliọnu mẹjọ Naira to jẹ ti NNPC/LNG ti wọn ko fi si apo asuwọn ijọba to yẹ ko wa.

Àkọlé fídíò,

Osun Election 2018: A ti gbaradì de ìdìbò Ọṣun bí ó ti yẹ- Adeoye

Bakan naa, Jimoh Moshood fikun wi pe awọn tun ri owo to le ni erinlelaadọfa milliọnu Naira lati ọwọ awọn osisẹ eleto idibo mejila lasiko idibo to waye ni Osu Kejila, ọdun 2016 ni ipinlẹ Rivers.

NNPC kéde Mele Kyari gẹ́gẹ́ bí aṣojú Nàìjíríà tuntun l'ájọ OPEC

Ajọ elepo rọbi lorilẹ-ede Naijiria, NNPC ti kede yiyan Mallam Mele Kyari gẹgẹ bii aṣoju tuntun fun orilẹ-ede Naijiria ni ajọ awọn orilẹede to n wa epo rọbi lagbaye, OPEC.

Ninu atẹjade kan ti ajọ NNPC fi sita lọjọ Aiku ni wọn ti kede rẹ pe Ọmọwe Ibe Kachickwu lo yan Kyari si ipo tuntun yii.

Atẹjade naa tun fi kun un pe, Mallam Mele Kyari to jẹ akọṣẹmọṣẹ imọ nipa epo rọbi wiwa yoo maa ti Minisita kekere fun epo rọbi, Ibe Kachukwu lẹyin ninu iṣẹ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

OsunDecides: Adeleke kò jáwọn olólùfẹ́ tó fẹ́ wòran ijó rẹ̀ kulẹ̀

Ṣaaju ipo tuntun yii, Mallam Kyari ni ọga agba fun ẹka to n ri si karakata epo rọbi ni ajọ NNPC.

Lara awọn iṣẹ ti yoo maa ṣe lẹnu ipo tuntun yii ni lilewaju ikọ orilẹede Naijiria lọ si igbimọ ọrọ aje lajọ OPEC.

Àkọlé fídíò,

Ọṣun Decides: ADC, ADP, APC àti SDP soju abẹ níkòó lórí ìwà ìbàjẹ́