Wenger: Ohun méje tí àwọn olólùfẹ́ Arsenal yóò rántí nípa rẹ̀

Arsene Wenger Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdún 1996 ni wọ́n gba Arsene Wenger sí ipò olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal

Loni ni Arsene Wenger, olukọni ikọ agbabọọlu Arsenal yoo gba ifẹsẹwọnsẹ rẹ to kẹyin gẹgẹ bii olukọni ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ni oṣu kẹrin ni Wenger kede pe oun yoo kuro nipo gẹgẹ bii olukọni ikọ agbabọọlu Arsenal lẹyin to ti lo ọdun mejilelogun nibẹ.

Laarin ọdun mejilelogun yii, oniruuru ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ eyi ti o sọ Wenger di olukọni to pẹ julọ ni ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ẹ jẹ ki a wo awọn ohun ti awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal atawọn ololufẹ ere bọọlu lagbaye yoo maa ranti Wenger fun lẹyin ti o ba lọ tan.

"Tani n jẹ Wenger?"

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdún méjìlélógún ló lò ní Arsenal

Ni ọdun 1996 ti wọn kede Arsene Wenger gẹgẹ bii olukọni tuntun fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, pupọ nínú awọn ololufẹ ikọ naa ni kò mọ ohunkohun nipa rẹ.

Nigba naa, orukọ rẹ ko tii di ilumọọka nitori ẹgbẹ agbabọọlu Monaco lorilẹ-ede france ni a lee pe ni ikọ to lorukọ julọ to ba ṣiṣẹ. Ni asiko ti a si n wi yii, iwọnba perete lawọn ti n wo liigi orilẹ-ede France lagbaye, paapaa julọ lorilẹ-ede Gẹẹsi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Wenger kini?" Wenger ewo?" ni ibeere to gba ẹnu pupọ awọn ti awọn oniroyin bi leere ọrọ nipa rẹ n sọ.

Arsenal di ẹgbẹ agbabọọlu ti n lepa ife ẹyẹ lọdọọdun

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fun igba akọkọ ninu itan liigi ilẹ Gẹẹsi, ikọ Arsenal gba ife ẹyẹ liigi lai fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan

Nigba ti Wenger gba akoso iṣẹ ni Arsenal, ni Arsenal di ikọ ti o n lepa ife ẹyẹ lọdọọdun.

Ni ọdun 1998 ati 2002, ife ẹyẹ meji-meji ni arsenal gba-ife ẹyẹ liigi ati FA.

Laaarin ọdun to fi wa ni Arsenal, ife ẹyẹ liigi ni mẹta ati FA meje ni Wenger gba.

Ikọ 'The Invincibles'Arsenal to gba liigi lọdun 2004 lai padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ni ọdun 1998 ati 2002, ife ẹyẹ meji-meji ni arsenal gba-ife ẹyẹ liigi ati FA

Fun igba akọkọ ninu itan liigi ilẹ Gẹẹsi, ikọ Arsenal labẹ akoso Arsene Wenger gba ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi lai fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan.

Eyi lo faa ti wọn fi fun ikọ Arsenal igba naa ni orukọ 'The Invisibles'eyi to tumọ si ikọ ti ko ṣee ba ta kangbọn.

Kikọ papa iṣire tuntun Emirate

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni wọn ri Wenger gẹgẹ bii 'Baba ijẹbu' ti ko fẹ na owo

Ọpọ lo ni igbagbọ pe kikọ papa iṣire igbalode Emirate fun Arsenal lati lo dipo Highbury ti wọn n lo tẹlẹ ri ni ibẹrẹ idamu Arsene Wenger gẹgẹ bii olukọni.

Arsene Wenger ṣe atọna ikọ naa ninu eyi ti wọn ko lee ra awọn gbajugbaja agbabọọlu nitori ọda owo pẹlu inawo papa iṣire tuntun wọn naa.

Ni ilẹ to mọ loni ikọ Arsenal lo fẹrẹ ni gbagede ere idaraya to yaayi julọ ni ilẹ Gẹẹsi, eyi ti ko ṣẹyin Arsene Wenger.

Ife ẹyẹ FA meje

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Laarin ọdun to fi wa ni Arsenal, ife ẹyẹ liigi ni mẹta ati FA meje ni Wenger gba

Titi di asiko ti Wenger fi n kuro ni ipo olukọni ẹgbẹ agbabọọẹu Arsenal, ko si olukọni to tii gba ife ẹyẹ FA tóo lorilẹ-ede gẹẹsi.

Igba meje ọtọọtọ ni Wenger ti gba ife ẹyẹ FA ko si si olukọni miran to tii gbaa.

Ifigagbaga Wenger ati Alex ferguson, Mourinho

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ lo gbagbọ pe kikọ papa iṣire igbalode Emirate ni ibẹrẹ idamu Arsene Wenger

Ni gbogbo ọdun mejilelogun to lo nipo, Wenger ati alex Ferguson to jẹ olukọni fun ikọ manchester United nigba naa kii wọn ọn laabọ funra wọn. Pupọ igba ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Manchester United ba ti fẹ waako ni awọn ololufẹ ikọ naa maa n reti ki awọn meji yii o gbe ina woju ara wọn.

Amọṣa, lẹyin ti Ferguson fẹyinti, Wenger ati olukọni ikọ Chelsea nigba naa Mourinho lo tun bẹrẹ itaporogan.

"Baba Ijẹbu" ati "Ahun"

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ni ilẹ to mọ loni ikọ Arsenal lo fẹrẹ ni gbagede ere idaraya to yaayi julọ ni ilẹ Gẹẹsi

Ọpọlọpọ ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni wọn ri Wenger gẹgẹ bii 'Baba ijẹbu' ti ko fẹ na owo lati ra awọn agbabọọẹu to lorukọ. Eyi si ti mu ki ọpọ ololufẹ ikọ agbabọọlu Arsenal o maa fi oju laabi wo o.

Sugbọn ọpọ igba pẹlu ni Wenger naa ti sọrọ sita pe, 'owo ti igbimọ adari ba fun mi ni mo n na