Prince Phillip: Ó di gbéré! Àrẹ̀mọ Phillip lọ! Àgbáyé ń dárò rẹ̀

Duke ti Edinburgh lọdun 1977
Àkọlé àwòrán,

Wọn bi Duke ti Edinburgh ni Greek island ti Corfu ni ọjọ kẹwa oṣu kẹfa ọdun 1921. Awọn iran rẹ jẹ idile oye lati Denmark, Germany, Russia ati Britain.

Lọjọ Ẹti ọjọ kẹsan osu kẹin ọdun 2021 ni Arẹmọ Phillip, ọkọ Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, Queen Elizabeth II jade laye.

Lati igba ti wọn si ti kede ipapoda rẹ l'awọn eekan lagbaye ti n daro rẹ. Awọn eekan ọmọ Naijiria pẹlu ko gbẹyin.

Aarẹ Muhammadu Buhari to wa ni asiko isinmi ni ilu London fi ọrọ ibanikẹdun rẹ ranṣẹ lorukọ orilẹede Naijiria si Ọbabinrin lori ipapoda ọkọ rẹ, Arẹmọ Phillip.

"Iku Duke ti Edinburgh jẹ opin ijọba kan. Arẹmọ Phillip jẹ ọkan lara awọn gbajumọ ti gbogbo oju mọ jakejado agbaye ati ti a o maa ranti ipa ti o ko ninu ajọ Commonwealth.

President Muhammadu Buhari extends his condolences to Her Majesty the Queen over the death of her husband Prince Philip who passed on peacefully at the age of 99.

Gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ ọ, Arẹmọ Phillip ko ipa ribiribi ninu ṣiṣe ẹyinju aanu paapaa itọju awọn ẹranko ti Ọlọrun da ati fun idagbasoke awọn ọdọ ni orilẹede to le ni aadoje lagbaye.

"Apẹrẹ manigbagbe ọkọ ni o jẹ to ti fẹ Ọbabinrin lati ọdun 1947," to si ni eyi jẹ iwuri lọpọlọpọ fun gbogbo igbeyawo ni oniruuru ipele ti wọn ba wa".

Bakan naa, aarẹ Buhari ba ijọba ilẹ United Kingdom kẹdun, ajọ Commonwealth fun bi wọn ṣe "padanu eekan agbaye yii".

Adari agba ajọ katakara lagbaye, WTO, Ọmọwe Ngozi Okonjo Iwealla ti ba Ọbabinrin ilẹ gẹẹsi, Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boriis Johnson, idile ọba at'awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi daro Arẹmọ Phillip, Duke of Edinburgh.

Ni pataki julọ Ọmọwe Iwealla na ọwọ ibanikẹdun rẹ si Ọmọba William, Duke of Cambridge leyi to ti ni ko mọkan ko si ṣe bi akin ni ipapoda Arẹmọ Phillips.

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Ninu ọrọ tirẹ, igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan ri, Atiku Abubakar sapejuwe iku Arẹmọ Phillips gẹgẹ bi eyi to mi gbogbo agbaye lọkan.

O ni gbogbo agbaye yoo ma ṣeranti awọn iṣẹ aanu ti Arẹmọ Phillip gbe ṣe nigna aye rẹ eleyi to ni o mu ki o jẹ baba isalẹ awọn ajọ ẹlẹyinju aanu to to ẹgbẹrin

Bakan naa ni Alaaji Atiku Abubakar tun yombo ipa to ko nipa sinsin ilẹ baba rẹ gẹgẹ bi ologun koda o ni gbogbo agbaye ko ni gbagbe aduroti rẹ fun Ọbabinrin Elizabeth keji.

Igbakeji aarẹ tẹlẹ naa wa gbadura pe ki Edua o duro ti idile ọba nilẹ Gẹẹsi ati gbogbo awọn eeyan ilẹ naa

Minisita orilẹede Naijiria fun ọrọ ilẹ okere, Geoffrey Onyeama naa sọrọ loju opo ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okere wipe ibanikẹdun ohun lọ sọdọ Ọlọlajulọ Ọbabinrin Elizabeth, idile rẹ ati gbogbo eeyan Great Britain lori ipapoda Duke ti Edinburgh.