Àbẹ̀wò Buhari: Gómìnà márùn-ún ki káábọ̀

Buhari n juwọ sawọn eeyan ni papakọ ofurufu ni ipinlẹ Jigawa Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Ṣaaju abẹwo yii, aarẹ ti kọkọ ṣabẹwo si ipinlẹ Taraba, Plateau, Benue ati Zamfara

Aarẹ Muhammadu Buhari ti gunlẹ si ipinlẹ Jigawa fun abẹwo ọlọjọ meji.

Gomina Abubakar Badaru ti ipinlẹ Jigawa, Abdullahi Ganduje tipinlẹ Kano, Ibrahim Geidam ti ipinlẹ Yobe, Abdullahi Abubakar ti ipinlẹ Bauchi, pẹlu Aminu Masari lati ipinlẹ Katsina, ni wọn wa nikalẹ lati gba Aarẹ Buhari lalejo ni papakọ ofurufu ilu Dutse.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ireti wa wi pe, Aarẹ Buhari yoo ṣe abẹwo sawọn iṣẹ akanṣe kan ni agbegbe Hadejia, Auyo ati Dutse ni ipinlẹ Jigawa lasiko abẹwo ọhun.

Image copyright @ImamShams
Àkọlé àwòrán Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ló jáde wá pàdé Ààrẹ Buhari nígbà tó gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfúrufú ní Dutse

Nibayii, Aarẹ Buhari ti wa ni Auyo lati ṣi ibudo ipese omi to wa ni Hadejia.

Wahala ọrọ aabo to gbode ni irinajo aarẹ da le lori

Iroyin sọ wi pe, ọgọọrọ awọn olugbe ipinlẹ naa ni wọn tu sita lati ki Aarẹ buhari kaabọ sibẹ.

Ṣaaju abẹwo yii, aarẹ ti kọkọ ṣabẹwo si ipinlẹ Taraba, Plateau, Benue ati Zamfara lori wahala ọrọ abo to gbode kan lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.