Iléẹjọ́ Kenya: Owó tí aya ná ni yóó gbà tí wọn bá túká

Ọwọ ọkọ ati iyawo kan pẹlu oruka igbeyawo lọwọ wọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ awọn obinrin agbẹjọro nilẹ Kenya fẹ ki wọn maa pin nkan ini wọn ni dọgba dọgba

Ile ẹjọ kan ni orilẹede Kenya ti dajọ pe, ofin igbeyawo ilẹ naa, eyi to fun ọkọ ati aya l'anfani lati ko nkan ini onikaluku wọn lọ, lẹyin ti wọn ba ti kọ ara wọn silẹ, ko lee mulẹ.

Ẹgbẹ awọn obinrin agbẹjọro nilẹ Kenya fẹ ki ofin naa yi pada,

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn fe ki lọkọ-laya ti wọn ba ti kọ ra wọn silẹ, maa pin nkan ini wọn ni dọgba dọgba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adajọ ni ẹnikẹni ko le wọnu igbeyawo ko si kuro pẹlu ohun to ju iṣẹ ọwọ rẹ lọ.

Ṣugbọn adajọ naa sọ pe, ẹnikẹni ko le wọnu igbeyawo ko si kuro pẹlu ohun to ju iṣẹ ọwọ rẹ lọ.

Ile-ẹjọ n9i ọrọ mọlẹbi ni.

Ni oṣẹ to kọja, ile ẹjọ to ga julọ l'orilẹede naa sọ pe, ohun ko lagbara lati gbẹjọ laarin awọn ọkọ ati iyawo kan ti wọn ti kọ'ra wọn silẹ.

Iyawo naa beere fun owo itọju lati ọwọ ọkọ rẹ ana. Ṣugbọn ile-ẹjọ naa sọ pe ọrọ mọlẹbi ni.