Yahoo Yahoo: Ọ̀pọ̀ olórin ti kọ́rin ìwúrí fún àgbéga rẹ̀

Ẹ̀rọ ayárabíàsá
Àkọlé àwòrán 'Yahoo-yahoo' tàbí 419, kìí ṣe tuntun ní Nàìjíríà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwà ọ̀daràn ni.

Ìwà ìlu-ni ní jìbìtì lórí ìtàkùn àgbáyé, tí àwọn kan tún n pè ní 'yahoo-yahoo' tàbí 419, kìí ṣe tuntun ní Nàìjíríà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwà ọ̀daràn ni.

Àwọn kan tilẹ̀ gbàgbọ́ pé, ara ọ̀nà àtijẹ ni, kìí ṣe ìwà ọ̀daran.

Kódà, kò yọ àwọn tó n kọrin sílẹ̀, nítorí pé àwọn kan lára wọn ti kọrin tó mú kó dà bí ẹni pé, wọ́n n kan sáàrá sí àwọn tó n ṣe é.

Wọ́n fi orin wọn ṣe ìgbélárugẹ fún iṣẹ́ ìlu-ni ní jìbìtì yìí, táwọn ọmọ Nàìjíríà nàá a sì maa jó sí àwọn orin nàá, bí ẹni pé jíjẹ́ 'ọmọ yahoo-yahoo' jẹ nkan tó dára.

Díẹ̀ lára àwọn orin tó tí gbóríyìn fún àwọn ọmọ yahoo, àti okòwò wọn ni yìí:

Orin ‘Yahoozee’ tí Olu Maintain kọ

Image copyright Olu Maintain/Instagram
Àkọlé àwòrán Orin Yahoozee gbaju-gbaja púpọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́

Ọdún 2008 ni Olu Maintain gbé orin ọhun, tó pè ní 'Yahoozee' jáde. Orin nàá gbajúmọ̀ púpọ̀ lásìkò nàá, débi pé, ó gba àmì ẹ̀yẹ Nigeria Entertainment Award, gẹ́gẹ́ bi orin tó tayọ jù lọ ní 2008.

Orin 'Maga don pay' tí Kelly Handsome kọ

Image copyright Kelly Hansome/Instagram
Àkọlé àwòrán Kò fẹ́ẹ̀ sí orin tó gbajúmọ̀ tó 'Maga don pay' tó jáde lọ́dún 2008

Ọdún 2008 nàá ni Kelechi Orji, tí ìnagijẹ rẹ̀ n jẹ́ Kelly Handsome, gbé orin 'Maga don pay' jáde. Ó tilẹ̀ máà fẹ̀ ẹ́ sí orin tó gbajúmọ̀ tó orin yìí lásìkò nàá. Nínú orin nàá ló ti sọ nípa bí 'maga', èyí tó túmọ̀ sí 'mumu' tàbí 'ọ̀dẹ́', tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ yahoo ṣe ń se.

Orin ‘Living Things’ tí 9ice kọ

Image copyright 9ice/Instagram
Àkọlé àwòrán Àjọ NBC f'òfin de orin 9ice tó fọnrere iṣẹ́ 'Yahoo'

Gbajú-gbajà olórin tàka-súfèé, Abọlọrẹ Akande, tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí 9ice, nàá gbé orin ọ̀hún tó polongo iṣẹ́ yahoo bí ọ̀nà ìwá n kan jẹ.

Orin náà tilẹ̀ tọ̀ka sí oríṣiríṣi ọ̀nà tí àwọn apani-lẹ́kún ọ̀hún n gbà ṣiṣẹ́ wọn. Bi i ká díbọ́n bí olólùfẹ́ lórí ẹ̀rọ ayélújára, ká fi lu ni ní jìbìtì, tàbí ká ṣe bí olókoòwò láti lu ẹni tí kò bá fura ní jíbìtì.

Àwọn orin tí à n gbọ́ ní ipalórí ìrònú àti ìgbé ayé wa

Àjọ tó n mójútó àwọ̀n iléeṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ní Nàìjíríà, NBC, tilẹ̀ f'òfin de àwọn iléeṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti má lo orin nàá.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn olórin gbọdọ̀ kó ara wọn ní ìjánu nípa orin tí wọn ń kọ lórí ìwà lílu jìbìtì.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, púpọ̀ nínú àwọn olórin yìí ló maa n sọ pé àwọn kò ṣe ìgbé lárugẹ fún 'yahoo' ṣíṣe, ohun tó dájí ni pé, àwọn orin tí à n gbọ́, tàbi ere tí à n wò, ní ipa tó n kó lórí ìrònú àti ìgbé ayé wa.

Tí a bá sì fẹ́ mú àdínkù bá àsà lílu èèyàn ní jìbìtì, àwọn olórin gbọdọ̀ kó ara wọn ní ìjánu nípa orin tí wọn ń kọ lórí ìwà lílu jìbìtì.