Ààwẹ Ramandan: Àwọn ouńjẹ tí a fi ń sínu àwẹ̀

Aworan eso
Àkọlé àwòrán Àwẹ Ramandan ń bẹ̀rẹ̀, irú ouńjẹ wo la lè jẹ?

Awọn ẹlẹsin Musulumi ni agbaye yoo bẹrẹ aawẹ Ramadan ni ọsẹ yii, eleyii ti yoo mu ki wọn yẹra fun jijẹ ati mimu lati owurọ titi di asalẹ.

Idi ti wọn fi n gba aawẹ yii ni lati bu ẹwa kun aye igbagbọ wọn ati ihuwa bi Ọlọrun, eleyii ti yoo mu wọn sun mọ Ọlọrun ati gbigbe igbe aye to wuyi, ti o si bu ọla fun Ọlọrun.

Ounjẹ jijẹ lasiko yii le jọ ohun ti ko lera, sugbọn eniyan gbọdọ sọra nipa ounjẹ ji jẹ lasiko aawẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẹ̀fọ́ rírò jẹ́ alábárìn iyán, fùfú, ẹ̀bà, àmàlà àti ìrẹsi funfun

Bi a se n ja awẹ ni asalẹ lasiko Ramadan

Eniyan gbọdọ sọra nigba ti eniyan ba n ja aawẹ ni asalẹ, ki eniyan ma baa da awọn eto to n jẹ ki ounjẹ walẹ lagọ ara rú.

  • Nitorina eniyan gbọdọ rọra jẹun nigba aawẹ Ramadan
  • Eniyan gbọdọ kọkọ mu omi ki o to jẹun
  • Eso dara lọpọlọpọ lasiko awẹ
  • Orisirisi ẹfọ tutu ati sise dara
  • Awọn ounjẹ oni koro bii ẹwa ati agbado naa dara
  • Miliiki ti ko ni adun igbalode naa dara lasiko naa.

Amọ, ounjẹ ajẹju o dara lasiko aawẹ Ramadan, ati wi pe sise ohun gbogbo ni iwon tuwon si lasiko Ramadan yoo jẹ ki ara ati ọkan eniyan o ji pepe.