Ìjọba: Zakzaky ń kó èrò jọ lọ́nà tó lòdì sófin

Sheik Ibrahim Zakzaky nílé ẹjọ́ Image copyright @ELBINAWI
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ Ajé ni wọ́n ti gbé asaájú ẹgbẹ́ Shiite naa wá sí ìlú Kaduna,

Asáájú ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Shiite, Sheik Ibrahim Zakzaky yọjú sílé ẹjọ́ giga ti Kaduna lọ́jọ́ ìsẹ́gun.

Déédé aago mẹ́jọ ààbọ̀ ni wọ́n gbé Zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ wá sílé ẹjọ́, tí ètò ààbò sì gbópọn gidi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pé alẹ́ ọjọ́ Ajé ni wọ́n ti gbé asaájú ẹgbẹ́ Shiite naa wá sí ìlú Kaduna, tí wọn sì fi pamọ́ sí ibití ẹnikẹ́ni kò mọ̀.

Image copyright @aayola81
Àkọlé àwòrán Àwọn alátìlẹyìn Zakzaky kò fi ijọba àpapọ̀ lọ́rùn sílẹ̀ lórí bó se fi asaájú wọn sí àhámọ́ ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ náà, ọ̀kan lára agbẹjọ́rò rẹ̀, Amòfin Maxwell Kyom ni lára àwọn ẹ̀sùn tí wọn fi kan Zakzaky ni pé ó ń kó àwọn èèyàn jọ, lọ́nà tó lòdì sófin, ìdìtẹ̀ hùwà ọ̀daràn àti ìwà pípa ọ̀pọ̀ èèyàn, èyí tí ikú jẹ́ èrè ẹ̀sẹ̀ rẹ̀.

Image copyright @ELBINAWI
Àkọlé àwòrán Ìjọba fi ẹ̀sùn kan Zakzaky pé ó ń kó àwọn èèyàn jọ, lọ́nà tó lòdì sófin

Amòfin kyon fi kun pé wọn kò leè tẹ̀síwájú lórí ẹjọ́ náà nítorí méjì nínú àwọn olùjẹ̀jọ́ ni kò yọjú sílé ẹjọ́.

Ó ní wọ́n bèèrè fún gbígba onídúró tọkọ-taya náà, àmọ́ adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà, Gideon Kurada ní kí òun kọ̀ ìbèèrè náà sínú ìwé.