Ilé aṣòfin Ọ̀yọ́: Ọlágúnjú Òjó di olórí ilé tuntun

Joshua Ọlágúnjú Òjó Image copyright NAtional Insight
Àkọlé àwòrán Igbakeji olori ile, Abdulwasil Musa Ojo lo ṣe akoso eto iyansipo lori ile tuntun

Joshua Olagunju Ojo ti di olori tuntun fun ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ.

Ojó gun akasọ ipo olori ile aṣofin naa lẹyin ti Michael Adeyemọ, to jẹ olori ile naa tẹlẹ ti jade laye ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2018.

Gba-gba-gba lawọn agbofinro raga bo gbagede ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ lasiko ti eto ati yan olori ile naa fi n waye.

Àkọlé àwòrán Wọ́n yan olórí tuntun lẹ́yìn tí olórí ilé tẹ́lẹ̀, Micheal Adéyẹmọ jáde láyé.

Yatọ si awọn aṣofin ati iwọnba perete oniroyin, ko si ẹnikẹni ti awọn agbofinro jẹ ko wọ gbagede naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji olori ile, Abdulwasil Musa lo ṣe akoso eto iyansipo lori ile tuntun naa.

Image copyright facebook/oyo state house of assembly
Àkọlé àwòrán Ojó gun akasọ ipo olori ile aṣofin naa lẹyin ti Michael Adeyemọ, to jẹ olori ile naa tẹlẹ jade laye

Joshua Ọlágúnjú Òjó ni olori awọ̀n ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlù tó kéré jùlọ ní ilé, náà kí ó tó di olórí ilé.

Bakannaa ni wọn tun yan Akeem Ademola, gẹgẹ bii olori awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere julọ nile aṣofin naa.