Buhari: N kò fi ìgbógun ti ìwà ìjẹkújẹ halẹ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni

Buhari n ṣi olu ileeṣẹ EFCC l'Abuja Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari ní kò sí ohun to leè yẹ ìpinnu òun láti gbógun ti ìwà ìjẹkújẹ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣi olu ileeṣẹ tuntun fun ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ to rọ mọ iṣuna lorilẹede Naijiria, EFCC nilu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ lasiko to fi n ṣe ifilọlẹ olu ileeṣẹ naa, Aarẹ Buhari ni, iṣejọba oun ko fi eto gbigbo-gun ti iwa ijẹkujẹ toun gunle, dunkoko mọ ẹnikẹni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ Buhari ni, ko si ani-ani lori ipinnu oun lati tubọ tẹra mọ gbigbo-gun ti iwa ijẹkujẹ.

Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán Olori ile aṣoju-ṣofin, Yakubu Dogara pe fun amojuto igbayegbadun awọn oṣisẹ ajọ EFCC

"Afojusun mi ni lati doju ija kọ iwa ijẹkujẹ lai wẹyin wo. Ohun ti iṣejọba mi n lepa ni lati daabo bo igbẹkẹle araalu. A ko wa lati fi eto igbogun ti iwa ibajẹ dun mọhuru-mọhuru mọ ẹnikẹni."

Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu obitibiti owo ti wọn fi kọ olu ileeṣẹ ajọ EFCC

Ninu ọrọ tirẹ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ olu ileeṣẹ ajọ EFCC naa, olori ile aṣoju-ṣofin, Yakubu Dogara ni, asiko to lati mojuto igbayegbadun awọn oṣisẹ ajọ EFCC, a si gbọdọ mu ayipada ba gule-gule iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu awọn alaṣẹ EFCC, fun obitibiti owo to to biliọnu mẹrinlelogun naira, ti wọn fi kọ olu ileeṣẹ naa.