Ìsúná 2018: N410bn ni àwọn asòfin fi lé ìsúná Buhari

Ile aṣofin agba Image copyright @bukolasaraki
Àkọlé àwòrán Tírílíọ̀nù mẹ́sán náírà ni àwọn aṣòfin buwọ́lù

Igbimọ ile asofin agba to wa feto isuna gbe abọ ayẹwo iṣuna ọdun 2018 siwaju ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria.

Ni ọjọ aje ni Sẹnetọ Danjuma Goje, to jẹ alaga igbimọ naa, gbe ayẹwo iṣuna naa si iwaju ile.

Ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ni awọn aṣofin agba kọkọ ti pinnu lati buwọlu aba naa, ṣugbọn to kuna lati ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ awuyewuye lo ti waye lori bi bibuwọlu aba iṣuna ṣe n falẹ niwaju igbimọ aṣofin apapọ, lati ọdun to kọja ti Aarẹ Buhari ti gbe e kalẹ niwaju ijoko apapọ awọn aṣofin agba ati awọn aṣoju-ṣofin orilẹede Naijiria.

Awọn aṣoju-ṣofin ni tiwọn ti kede pe, ọjọọru ni awọn yoo buwọlu abadofin eto iṣuna oni tiriliọnu mẹsan-an o le diẹ naa.

Image copyright @AsoRock
Àkọlé àwòrán Tiriliọnu mẹjọ ati ẹgbẹta biliọnu, N8.61 trilion, ni aba iṣuna ti aarẹ Buhari ṣeto siwaju awọn aṣofin apapọ

Aba eto iṣuna ti ile aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin panupọ le lori, fi irinwo o le mẹwa biliọnu naira ga ju eyi ti aarẹ gbe ka iwaju awọn aṣofin apapọ.

Tiriliọnu mẹjọ ati ẹgbẹta bilisnu, N8.61 trilion, ni aba iṣuna ti aarẹ ṣeto siwaju awọn aṣofin apapọ, ṣugbọn lẹyin ijiroro gbogbo ẹka ile mejeeji fẹnuko si tiriliọnu mẹsan o le ọgọfa biliọnu naira, N9.12 trilion.