Irinṣẹ́ òǹkà ọdún ti wà láti ka iye ọdún tó leè lò láyé

Njẹ́ o mọ̀ pé, iye ọdún tó ṣeé ṣe kí gbogbo ènìyàn lò láyé, ti fi ọdún méje pọ̀ si láti ọdún 1990?

Irinṣẹ́ òǹkà ọdún yìí, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìṣìrò tìrẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú orílẹ̀èdè to ti wá.

Ọdun mejilelaadọrin nireti wa pe o jẹ ọdun to kere ju ti ẹda yoo lo laye - aadọrin ọdun fun ọkunrin, marundinlọgọrin fun obinrin. Ṣugbọn, eyi n yipada pẹlu ọjọ ori. Fun apẹẹrẹ,ireti wa pe ẹni ti o ti pe ọdun mọkandinlaadọrin yoo lo ọdun mẹtadinlogun si.