Saraki ni ọ̀gá ọlọ́pàá, Ibrahim Idris fẹ́ lo àwọn ọ̀daràn láti parọ́ mọ́ òun

Bukola Saraki Image copyright Bukola Saraki
Àkọlé àwòrán Sẹnetọ Bukọla Saraki ni ọga agba ọlọpa lorilẹede Naijiria, Ibrahim Idris n gbero lati hun panpẹ akoba kan fun oun

Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki ti ke gbajare sita pe ọga agba ọlọpa lorilẹede Naijiria, Ibrahim Idris n gbero lati hun panpẹ akoba kan fun oun.

Nigba to n sọrọ nibi ijoko ile lọjọọru, Sẹnetọ Saraki ni Ọga ọlọpa n gbero lati lo awọn afunrasi ẹlẹgbẹ okunkun kan ti ọwọ ọlọpa ba ni ilu ilọrin ti wọn si ti bẹrẹ eto ati ṣe ẹjọ wọn lati parọ mọ ohun ati awọn eekan oloṣelu kan ni ipinlẹ Kwara pe awọn ni baba isalẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Iwadi ti pari, eto si ti nto lati gbe wọn lọ siwaju ile ẹjọ ni ibamu pẹlu amọran olupẹjọ agba nipinlẹ Kwara. Ṣa dede ni wọn ni ọga agba ọlọpa ni ki wọn ko wọn wa si ilu Abuja.

Iroyin ti mo si n gb ni pe wọn fẹ wa ọna ti wọn yoo fi yii akọsilẹ ti wọn kọ nilu Ilọrin pada lati fi ẹsun kan ijọba ipinlẹ Kwara, paapaajulọ emi."

Image copyright Nigeria Senate
Àkọlé àwòrán Ọ̀gá ọlọ́pàá, Ibrahim Idris àti àwọn aṣòfin ti ń gbéná wojú ara wọn fún ìgbà pípẹ́

Ile aṣofin agba kọminu lori igbesẹ yii ti wọn si ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bii 'iwa idunkokomọni ati ibanilorukọ jẹ.'

Ninu ọrọ to sọ, Sẹnetọ Mishau ni oun ti pe akiyesi ile si 'iwa ijẹgaba ati idunmọhuru mọni lati ileeṣẹ ọlọpaa ni nkan bii ọdun kan sẹyin pe gbogbo wa ni ọga ọlọpaa yii yoo ṣi fi oju rẹ ri rẹdẹrẹdẹ.'

Amọṣa, gbogbo awọn aṣofin agba naa lo fẹnuko pe ki ile aṣofin agba o gbe igbimọ kalẹ ti yoo lọ ṣepade pẹlu Aarẹ Buhari lori ọrọ naa.