Koko iroyin: Ọmọge Campus d'olóògbé, Ilé Aṣòfin fòǹtẹ̀ lù àbá ìsúná 2018

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

Àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn gba ẹ̀mí ìlúmọ̀ọ́ká òsèrè tíátá, Aisha Abimbọla

Àkọlé àwòrán,

Lara tiata ti Aisha se ni Omoge Campus

Gbájú-gbajà òsèré tíátà obìnrin, Aisha Abimbọla, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ‘Ọmọge Campus’ tí jáde láyé ní orílẹ̀èdè Canada.

Aisha ni ìròyìn gbalẹ̀ kan ní ààrọ̀ ọjọ́rú lórí ìtàkùn àgbáyé pé ó ti mí kanlẹ̀ lásìkò àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ.

Ilé Aṣòfin buwọ́ lu àbá ìsúná 2018

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Àkọlé àwòrán,

Ile aṣofin mejeeji gbe aba naa lọ si triliọnu mẹsan o le diẹ.

Ile igbimo Aṣofin agba orilẹede Naijiria l'Abuja ti f'ọwọ si abadofin eto isuna fun ọdun 2018 .

Tiriliọnu mẹjọ ati ẹgbẹta biliọnu, N8.61 trilion, ni aba iṣuna ti aarẹ ṣeto siwaju awọn aṣofin apapọ, ṣugbọn lẹyin ijiroro, gbogbo ẹka ile mejeeji fẹnuko si tiriliọnu mẹsan o le ọgọfa biliọnu naira, N9.12 trilion. E ka ekunrere re ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

IVF: Bí ẹyin àti àtọ̀ ṣe ṣe sí la fi ń mọ̀ irú ọmọ tí yóò jáde

Àkọlé fídíò,

Ọ̀nà àbáyọ sí àìrọ́mọbí tọkùnrin tobìnrin