Ìsekú pani lọ́jọ́ ìbò: Mọ̀lẹ́bí aláìsí ń bẹ Ajimọbi

Gómìnà Abiọla Ajimọbi Image copyright @oyostategovt
Àkọlé àwòrán Àwọn òbí ọmọ tó sàìsí ti ń késí gómìnà Abiọla Ajimọbi láti se ìdájọ́ òdodo

Ọjọ́ burúkú, èsù gbomimu ni ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kejìlá osù Karùn-ún, ọdún 2018 jẹ́ fún ìdílé Lateefat Abubakar, tíí se ọmọde-bìnrin ẹni ọdún méjìdínlógún tí wọn yìnbọn mọ́ ní ọjọ́ tí ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àdúgbò Ìdí Òro ní ìlú Ìbàdàn la gbọ́ pé àwọn òsìsẹ́ ààbò ara ẹni, ni ààbò ìlú, táa mọ̀ sí Civil Defence, ti yìnbọ mọ́ ọmọdébìnrin náà lásìkò tó lọ ra òògòn fún àìlera ara rẹ̀.

Ní báyìí, ìwé ìròyìn Punch ní, àwọn òbí ọmọ náà ti ń késí gómìnà Abiọla Ajimọbi àti àwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni láti sèrànwọ gba ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bàbá Aláìsí náà, Kọlawọle Abubakar ni gómìnà Ajimọbi gan kò tíì wá se àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí ìdílé òun.

Àbúrò ológbèé, Gbemisọla ní "ìdájọ́ òdodo ni à ń bèèrè. Irọ́ ńlá sì ni pé ìbọn òsìsẹ́ Civil Defence náà sèèsì yìn lásìkò tó ń bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ rẹ̀."