Olósèlú: Àpótí Sobàtà bíi èèlò ìróni-lágbára sàn ju ebi lọ

Isu bii ohun eelo ironi lagbara Image copyright Babawo
Àkọlé àwòrán Babawo se siọ̀ awọn eeyan to n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ naa lori itakun agbaye

Ọ̀pọ ọmọ Naijiria la ẹnu silẹ lai lee pa de nigbati Kọmisana feto ẹkọ giga ni ipinlẹ Borno,Usman Jaha Babawo, pin awọn ohun eelo ironi lagbara fawọn ọdọ to wa lẹkun idibo rẹ.

Kii kuku se awọn ohun eelo to pin lo n se awọn araalu ni haa-hin, bi ko se irufẹ awọn ohun eelo naa, eyi to n kọ wọn lominu.

Lara awọn ohun eelo naa lati ri apoti sobata, burọọṣi inubata, ori inubata, taa mọ si pọliiṣi ati fukẹ́-fukẹ́ inubata, taa mọ̀ si foam, asọ, mọto ati ẹrọ iransọ.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Oniruuru awọn eroja apanilẹrin lawọn oloselu maa n pin bii ohun eelo aroni lagbara

Taa ba si wo daada, kii se Babawo ni yoo kọ̀kọ̀ pin awọn ẹbun ironi laagbara ti yoo kọ awọn ọmọ Naijiria ni ominu bayii, nitori a ti gbọ nipa awọn oloselu ati awọn gomina kan ti wọn ti kọkọ pin awọn ohun eelo ironi lagbara bii tii alagbada, taa mọ si Lipton tea, eroja Noodles, ẹyin adiẹ, garawa ipọnmi ati ọmọ-lanke ti wọn n pe ni wheel barrow.

Bẹẹ ba si gbagbe, gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom naa ti pin ọmọlanke ri fawọn eeyan ipinlẹ rẹ bii ohun eelo ironi-lagbara, eyiti okiki rẹ gbalẹ kan nigba naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi lo wa mu ki BBC Yoruba kan si araalu kan lati beere pe oju wo lo fi wo igbesẹ yii ? N jẹ iwa ipese idẹrun fun araalu ni eyi abi iwa tita abuku wọn.

Lero ti Alagba Olu Israel, apa oke ọya ni iwa pinpin awọn ohun eelo ironi lagbara to jẹ kayeefi yii wa, ọna lati jẹ gaba lori awọn araalu si ni.

Ẹ gbọ Alagba israel siwaju sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈèlò ìróni-lágbára, fún ìdẹ́rùn ni àbí àbùkù

Niwọn igba to jẹ pe a gbọ́ ẹjọ ẹnikan da, agba osika ni. Ọna lati mase role apakan, da apakan si, lo mu ki BBC Yoruba kan si Kọmisana to pin apoti sobata naa ni ipinlẹ Borno, Hon Babawo.

Image copyright Babawo
Àkọlé àwòrán Babawo ni ko si ohun to buru ninu apoti sobata ti ohun pin

Lero tiẹ́, o ni ko si ohun to buru ninu apoti sobata ti ohun pin yii, nitori ohun ti awọn ọdọ naa n fẹ ni eyi, wọn si mọọmọ beere lọwọ ohun ni.

Babawo ni miliọnu mẹta naira ni oun na lori ipese awọn eroja sobata naa, fawọn ọdọ yii, ti wọn jẹ ọmọ orukan, ti ogun Boko Haram ti pa awọn obi wọn.

Image copyright Babawo
Àkọlé àwòrán Babawo ni miliọnu mẹta naira ni oun na lori ipese awọn eroja sobata

Ko sai wa se siọ̀ awọn eeyan to n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ naa lori itakun agbaye, to si ni ailaju lo n da irufẹ awọn eeyan yii laamu nitori awọn eeyan to n so bata gan wa lawọn orilẹede to ti goke agba bii Amerika, canada, ati Gẹẹsi.