FIFA: Super Eagles bọ́ sí ipò kẹrin ní Afrika

Mikel atawọn akẹgbẹ rẹ n dawọọ idunnu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orílẹ̀èdè Germany ló ń léwájú lórí atẹ ìgbéléwọ̀n FIFA

Ipo kẹtadinlaadọta ni orilẹede ẹgbẹ agbabọọlu Super eagles Naijiria ṣi wa, lori atẹ igbelewọn awọn orilẹede to n gba bọọlu lagbaye fun oṣu karun eleyii to jade lọjọbọ.

Amọ ni ilẹ Afirika, ipo kẹrin ni Super Eagles sun si bayii lati ipo kẹfa ti wọn wa tẹlẹ.

Awọn ikọ agbabọọlu orilẹede Argentina, Croastia ati Iceland ti Super Eagles yoo koju, ni idije ife ẹyẹ agbaye wa ni ipo karun-un, ikejidinlogun ati ikejilelogun ni ṣisẹ n tẹle, lori atẹ igbelewọn awọn orilẹede to n gba bọọlu lagbaye.

Orilẹede Germany lo ṣi n gbe ipo kinni, ti brazil si n tẹle e.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: