NDLEA: A kò tíì mọ àwọn tó ni Tramadol náà

Aworan tramadol Image copyright NDLEA/Twitter
Àkọlé àwòrán Àjọ NDLEA ti gbésèlé tọ́ọ̀nù mẹ́rin Tramadol

Àjọ NDLEA ti gbésèlé tọ́ọ̀nù mẹ́rin Tramadol ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Mohammed ìlú Èkó, bẹẹ ni ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ pàṣẹ pé kò gbọdọ̀ sí lórí àtẹ mọ́,

Ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA, Ahmadu Garba ló sàlàyé ọ̀rọ̀ ọ̀hún, fún àwọn akọròyìn pé ọ̀nà méjì ni wọ́n gbé tramadol òhún gbà wọ inú ìlú láti orílẹ̀-èdè India, tí àwọn sì ríi gbà ní ibùdó ìkẹ̀rùsí ilé iṣẹ́ náà tó wà ní pápákọ̀ òfurufú ìlú Èkó.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àjọ NDLEA kò ní oore ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn tó fi òògun òhún ráńṣẹ́, bákan náà kò sí ẹnikẹ́ni tó wá láti gba a kúrò ní pápákọ̀ òfurufú.

Garba ní àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí àwọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ló ta àjọ òun lólobó nípà òògùn Tramadol tó fẹ́ wọlé pèlú ọkọ̀ òfurufú United Arab Emirate.

Image copyright NDLEA/Twitter
Àkọlé àwòrán Garba ní àjọ ọ̀tẹlẹ̀mú tí àwọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ló ta àjọ òhun lólobó nípà òògùn Tramadol tó fẹ́ wọlé

Ó sàlàyé pé, àjọ NDLEA ti gbésẹ̀lé kílò òògùn olóró mẹ́tàdínláàdọ́rún-ún láàárín oṣù kínní ọdún sí oṣù kẹrin ọdún yìí.