Ìgbéyàwó Ọmọọba: Ọjọ́ márùn-ún ni wọn fi se àkàrà òyìnbó

Ìgbéyàwó Ọmọọba Ìlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Harry àti ìyàwó Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbéyàwó Ọmọọba Ìlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Harry àti ìyàwó rẹ̀ yóò wáyé lọ́la

Ìrọ́-kẹ̀kẹ̀ ti gbode kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní báyìí tí ìgbaradì ti dé ojú ọ̀gbagadè fún ìgbeyàwó Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀, Meghan Markle.

Bí ìmúrasílẹ̀ ìgbéyàwó náà ṣe n kásẹ̀ nlẹ̀ di ọjọ́ Àbámẹ́ta báyìí, kò tíì sí ẹni tí yóò dúró gẹ́gẹ́bíi bàbá ìyàwó ni ibi àyẹyẹ náà, tí yóò wáyé ni ilé ìjọsìn St. George.

Ìyawó ọ̀la, Meghan Markl,e gbé àtẹ̀jáde kan síta ní Ọjọ́bọ pe bàbá òun, Thomas Markle, kò ní lè wá sí ibi ìgbéyàwó náà, kó bàá lè tọ́jú ara reẹ̀.

A gbọ́ pé ìyá ìyàwó Doria Ragland, yóò lọ kí Ọbabìnrin Elizabeth fún ìgbá kínní lónìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ní báyìí ná, wọ́n ti gbé fọ́tò àkàrà òyìnbó tí ọgọ́rùń mẹ́fà àwọn àlejò Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀, Meghan Markle yóò jẹ, ní ibi ìgbéyàwó wọn ti yóò wáyé lọ́la jáde báyìí.

Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Claire Ptak ń ṣiṣẹ́ lórí àkàrà òyìnbó náà

Fọ́tò náà ṣe àfihan Claire Ptak, tó ń ṣiṣẹ́ lórí àkàrà òyìnbó náà nínú ilé ìdáná ààfin Ọbabìnrin Elizabeth, ti a mọ̀ sí Buckingham Palace ni ọjọ́ Ọjọ́bọ.

Ọjọ́ márùń ni la gbọ́ pe Ptak àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mẹ́fà ti ń ṣiṣẹ́ lórí àkàrà òyìnbó náà.

Image copyright PA
Àkọlé àwòrán The cake is being decorated with a white, elderflower Swiss meringue buttercream