Ìdìbò 2019: Fani-Kayode ní kí Buhari gbáradì fún ìfẹ̀yìntì

Femi Fani-Kayode àti Ààrẹ Muhammadu Buhari
Àkọlé àwòrán,

ọ̀rọ̀ ń bọ́ mokó morò bọ̀ lórí ìdìbò ààrẹ ọdún 2019

Minisita tẹlẹ ri fun ile iṣẹ ọkọ ofurufu lorilẹede Naijiria Femi Fani-Kayode ti sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko mura silẹ fun ifẹyinti lọdun 2019.

Fani-kayode sọrọ naa loju opo Twitter rẹ nigba ti o n ki Atiku Abubakar ku oriire lẹyin ti o jawe olubori gẹgẹ oludije fun ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP lọjọ Aiku.

O fi kun ọrọ rẹ pe ki ẹgbẹ oselu APC mu ra silẹ fun ogun ninu idibo Aarẹ ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti kí àwọn olùdíje ẹgbẹ APC ni kakakiri orilẹede Naijiria ku oriire, bẹẹ ni o tun rọ wọn ki wọn ma ṣe binu si ara wọn.

Atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ rẹ Garba Shehu rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati ma sa kuro ninu ẹgbẹ nitori pe wọn ko wọle ninu idibo abẹle ẹgbẹ APC.

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ni oun ṣetan lati ṣe ijọba lai fi ti ẹ̀yà kankan ṣe

Àárọ ọjọ Aiku ni iyawo aarẹ Aisha Buhari fi ẹhonu han nitori pe o ni awọn idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC ko lọ deede. O sọ ninu ọrọ rẹ wipe, o to ki eeyan yéra fun ẹgbẹ oṣelu naa.

'Ẹ wo àwokọṣe Ambode'

Atẹjade aarẹ ni,"Ninu idije, eniyan kan a bori, ẹlomiran a ja kulẹ. Ṣugbọn awọn to ja kule ko gbọdọ sa kuro ninu ẹgbẹ taki ki inu wọn ma dun si ẹgbẹ mọ. Awọn oloṣelu gbọdọ fi ti Gomina Akinwunmi Ambode ti Ipinlẹ Eko kọgbọn. Bo tilẹ jẹ pe o ja kulẹ, ko fi ibinu sa kuro ninu ẹgbẹ."

Ṣaaju, Aarẹ Buhari ni ina ijọba ti gbooro si, awọn ti sẹgun Boko Haram de ibi to lamilaaka ati pe eto isuna fun awọn onisowo n ran ọpọlọpọ eniyan lọwọ.

Aarẹ naa wa fikun pe awọn ko ni kawọ gbera ti awọn ba wọle ẹlẹẹkeji, ati pe oju rere ti awọn ara oke fi n wo orilẹ-ede Naijiria bayiii yoo tẹsiwaju.

Aarẹ Buhari nìkan ni wọn fà kalẹ̀ pé kò ṣoju wọn ninu ẹgbẹ APC.

Ẹgbẹ̀rún méje aṣojú ti yan Buhari lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ ti kọkọ dibo to ti ni 14, 842, 072 ìbò ki wọn to wa kéde rẹ̀ bayii ni Eagle Square.

Àkọlé àwòrán,

Aare Buhari yoo ni anfani lati dije lẹẹkansii gégé bii aarẹ Naijiria

Buhari ni yoo dije dupò pẹlu ẹnikẹni ti ẹgbẹ oṣelu PDP bá fa kalẹ atawọn ẹgbẹ oṣelu to ba kù ninu ẹgbe mokanlelọgọrun ti ajọ eleto idibo INEC kede.

Ìdìbò ẹgbẹ APC láti kéde Buhari ni Eagle Square

Àkọlé àwòrán,

Awọn ẹgbẹrun meje aṣoju ni yoo yan Aarẹ Buhari

Àago mọ́kànlá alẹ́ ni ìdìbò abẹ́lé ti ẹgbẹ oṣelu APC ti o n waye ni Eagle Square, ni ilu Abuja yoo bẹ̀rẹ̀ nibi ti fi ontẹ lu Aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹbii ẹni ti yoo dije du'po aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oselu naa ni ọdun 2019.

Buhari nikan ni ẹgbẹ oṣelu naa fa kalẹ lati dije.

Bẹẹ ni nilu Eko, Sẹ́nétọ̀ Gbenga Ashafa ti já kulẹ̀ nínú ìdíje abẹ́le ti ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aṣoju ẹkùn ilà oorùn Eko (Lagos East) ni Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà.

Ipinlẹ Eko yan awọn aṣoju ti yoo dupo senetọ ni Abuja

Àkọlé àwòrán,

Bayo Oshinowo ní ìbò 247,743 nigba t Gbenga Ashafa ní ìbò 20,385

Alatako rẹ Bayo Oshinowo ní ìbò 247,743 nigba ti Ashafa ni ibo 20,385.

Bakan naa, Olamilekan Solomon (Iwọ oorun) jawe olu bori pẹlu ibo 378,906 nigba ti alatako rẹ Kayode Opeifa ni ibo 1,179.

Nitori naa, àwọn sẹnetọ ti yóò díje ni APC Eko ni Rẹmi Tinubu (Aarin gbungbun) Olalekan Yayi (Iwọ oorun) àti Bayo Oṣinọwọ (Ila oorun).

Remi Tinubu yoo jade laini alatako kankan ninu idibo abẹle ẹgbẹ APC naa.

Bakan naa, ẹgbẹ oselu APC ti sun ipade gbogboogbo rẹ si iwaju di irọlẹ Ọjọ Kẹfa, Ọsu Kẹwa, ọdun 2018.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ APC fi sita ni ọjọ ipade naa sọ pe wọn gbe igbese naa ki awọn eniyan to n bọ lati awọn ipinlẹ le de ibi ti ipade naa yoo ti waye lasiko.

Atejade naa ni awọn asoju lati ipinlẹ kọọkan yoo se ayẹwo kaadi ẹgbẹ wọn ni papa isere Old Parade Ground labuja ki wọn to wa peju si Eagles Square nibi ti ipade naa yoo ti waye.

Eto idibo abẹle ni ẹgbẹ APC ipinlẹ Jigawa:

Gomina Badaru ti ipinlẹ Jigawa lo jawe olubori gẹgẹ bi oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Jigawa.

Oríṣun àwòrán, @Saifullahi_Abas

Àkọlé àwòrán,

Gomina Badaru Abubakar

Apapọ ibo ẹgbẹrun mẹta le mẹtalelọgọfa, 3123 lati fẹyin Ubale Hashin to ni ibo mẹrinlelaadọta, 54. Kiiṣe ilana tuntun ti ẹgbẹ APC gbekalẹ ni wọn lo fun eto idibo naa.

APC primary: Nkan kò tìí ṣẹnu ire fún àná Gómìnà Rochas ní Imo

Ọkọ ọmọ Rochas Okorocha to jẹ gomina ipinlẹ Imo, Uche Nwosu, ti padanu ni wọọdu kan ninu idibo abẹlẹ APC fun oludije si ipo gomina.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ wi pe ko si ẹni to dibo fun Nwosu ni wọọdu naa.

Àkọlé àwòrán,

Oludije keji Hope Uzodinma to jẹ ọmọ wọọdu kan naa pẹlu Nwodu lo gba gbogbo ibo aadọrun naa.

Oludije keji, Hope Uzodinm, a to jẹ ọmọ wọọdu kan naa pẹlu Nwodu lo gba gbogbo ibo aadọrun naa.

Idibo naa waye ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Unity Primary School, Umuchoke Amaigbo ni ipinlẹ Imo.

Awọn oludibo ṣi n duro lati dibo ni wọọdu Okorocha to jẹ gomina ipinlẹ Imo.

APC Primary: Wọ́n yọ Balogun Fulani gẹ́gẹ́ bí alága APC

Ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress n lọ jákè-jádò àwọn ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà yàtò si Eko, àti Imo.

Àkọlé àwòrán,

Wan ni kí alága APC ní Ìpínlẹ̀ Kwara lọ rọ́ kún ńlé

Bósẹnlọ l'áwọn ìpínlẹ̀:

Rivers:

Awọn ẹka ti Abe ti n dibo lọ nipa lilo ìbò gboogbo ti yoo fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ laaye lati dibo nigba ti awọn ẹka ti Rotimi Amaechi n péjọ si olu ilé ẹgbẹ APC ni Porthacourt lati dibo nipa lilo ibo awọn aṣoju.

Àkọlé àwòrán,

Ile iya egbe APC ni Rivers nibiti awon eka Amaechi ti n pejo fun idibo won

Ipinlẹ Kwara:

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe ki igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Kwara labẹ alaga Ishola Balogun-Fulani lọ rọ kun nile.

Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu APC, Yekini Nabena, lo fi ọrọ naa lede nibi idibo abẹle ẹgbẹ ọhun lọjọ Aiku.

Bakan naa ni ọgbẹni Nabena kede pe ẹgbẹ APC ti sun idibo abẹle to yẹ ko waye ni ipinlẹ Ogun, Zamfara, Bauchi ati Abia si ọjọ Aje.

Ọyọ:

Adebayọ Adelabu ni wọn dibo yan lati dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ l'ọdun 2019.

Adelabu to ti figba kan jẹ igbakeji gomina banki apapọ Nigeria, CBN, gbegba oroke nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ to waye l'ọjọ Aiku, ni papa iṣere Adamasingba, niluu Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Adebayo Adelabu/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Adelabu ti figba kan jẹ igbakeji gomina banki apapọ Nigeria, CBN.

Eyi waye lẹyin ti awọn alatako rẹ bi i Joseph Tegbe, ti awọn kan gbagbọ pe oun ni ẹni ami ororo Gomina Abiọla Ajimọbi, ati awọn oludije mi i finu-findọ jawọ ninu eto idibo naa, ayafi Amofin Adeniyi Akintọla to ni dandan ni ki wọn jẹ ki eto idibo waye fun gbogbo oludije.

Ṣugbọn, o ku diẹ ki eto idibo bẹrẹ ni Akintọla naa sọ pe oun yọnda fun Adelabu.

Àkọlé àwòrán,

Ero pọ to ti jade lati wa yan oludije APC nipinlẹ Ọyọ nibiti oludije meje ti n dije

Adebayọ Adelabu jẹ ọkan lara awọn ọmọọmọ gbaju-gbaja oloṣelu niluu Ibadan, Adegoke Adelabu, ti gbogbo eniyan mọ si Pẹnkẹlẹmẹẹsi.

Kwara:

Hon. AbdulWahab Omotose Kayode ti jawe olubori nínu idibo abẹlẹ ipinlẹ Kwara gẹgẹ bi oludije.

Àkọlé àwòrán,

Akọroyin nigba kan ri ni yoo ṣoju APC dupò gomina Kwara

O ti ṣiṣẹ pẹlu ileeṣe iwe iroyin THISDAY ri, ko to wọle di olori awọn ọmọ ile igbimo asofin to kere ju nipinlẹ Kwara.

Àkọlé àwòrán,

Alhaji Kayọde tó jáwé olúborí ní Kwara ti di oludije dupò gomina

Seriki Yahaya ní ìbò 6, Abdulrahaman Abdulrazaq, ní ìbò 3, Garba Gobir ní ìbò 2, Akeem Oladimeji Lawal ní ìbò 27, Lukman Mustapha ní ìbò 11, Mashood Mustapha ní ìbò 5, Modibo Kawu ní ìbò 2, Mohammed Belgore, SAN ní ìbò 6, Professor ShuaibAbdulraheem ní ìbò 5, Mallam Saliu Mustapha ní ìbò 12, Yaman Abdullahi ní ìbò 7 ati Alh Tajudeen Makama ní ìbò 4, nigba ti Kayọde ni 891.Ibo mejila ni wọn wọgile. Laaarin ariwo ayò ati idunnu ni Hon. Christopher Ayẹni ṣe ikede èsi idibo yii. O ni idibo ẹka ti wọn ni ajọ INEC yoo gba wọle fun idibo gangan.

Oludije yii fidunnu rẹ han pẹlu ileri pe oun yoo saipa oun ki ẹgbẹ APC wọle lọdun to m bọ̀.

Ki lo ṣẹlẹ ni idibo abẹlé Kwara tẹlẹ?

Hon. Christopher Ayeni, to jẹ akọwe ẹgbẹ APC ti ipinlẹ Kwara ni àwọn oludije mẹtala naa ni wọn ti pegede gba ami o yege lati dije dupò gomina ni Kwara.

Àkọlé àwòrán,

Onikaluku ni eka Filani n dibo yan eni to fe

Bakan naa lo ṣalaye pé awọn oludibo 1007 to jẹ aṣoju lo n kopa ninu idibo naa nibiti ko ti si wahala kankan ti gbogbo rẹ n lọ bi o ti yẹ.

Àkọlé àwòrán,

APC pin si meji ni Kwara, awon kan n dibo loni

Hon Ishola Balogun-Filani to jẹ alaga ẹgbẹ APC ni Kwara ba BBC Yoruba sọrọ lori idibo naa pe ẹka ti wọn to n dibo loni ni ajọ INEC yoo gba wọle nitori pe aṣẹ wa lati òkè pé ki awòn ṣeto idibo naa loni ni.

Enugu:

O ni àwọn alatilẹyin Ogara George Tabugbo to jẹ ọkan lara awọn oludije sipo gomina ni Enugu ya bo ibudo idibo naa ni eyi to di wahala ti awọn to fẹ ṣeto idibo ọhun tẹlẹ si kuro.

O ni ko pẹ lẹyin eyi ni àwọn agbofinro fi ẹsẹ fẹẹ lẹyin ti awon alatilẹyin awọn oludije tutọ soke.

Koda ọkan ninu awọn oniwahala naa kọlu akọroyin ti wọn si ba ẹrọ ibanisọrọ rẹ jẹ.

Awọn akọroyin BBC ṣi n duro wòye boya idibo naa a tẹsiwaju tabi bẹẹ kọ́.

Ki lo ṣẹlẹ ni idibo abẹlé Enugu tẹlẹ?

Akọroyin BBC to wa nipinlẹ Enugu ni oriṣii ẹ̀ka meji ni awọn oludibo pin si ni awọn ibudo idibo abẹlẹ to n lọ lọwọ.

Àkọlé àwòrán,

Awon oludije to ni àmì yii ni won n je ki won wole dibo fun oludije to wu won ni Enugu

Awọn agbatẹru ibo ni Enugu ti ya awọn oludibo si ọtọọtọ nipa wiwo iru ààwọ̀ kaadi idbo ti won ba muwa sibudo idibo.

Àkọlé àwòrán,

W#on ko faaye gba awon oludibo to niru kaadi yii lati wo ibudo idibo ki won dibo yan oludije ti won fẹ́ ni Enugu

Awọn agbofinro NSCDC ati ọlọpaa ti n de si àwọn ibudo idibo l'Enugu bi ti UNEC ni aarin gbungbun Enugu

Àkọlé àwòrán,

Eto Idibo abẹlẹ yii n mu ọwọ agbofinro dani fun aabo ni Enugu

Ogun: Kò tìí dábì pé ètò ìdìbò abẹ́lé yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Ogun. Àwọn ìròyìn kan sọ pé wọ́n ti sún ọjọ́ ìdìbò nàá síwájú nígbà tí àwọn kan tún sọ pé irọ́ ni.

Alága ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Ogun, Olóyè Derin Adebiyi tó bá BBC sọ̀rọ̀ ní nkan bii aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú tó yẹ kí ìdìbò nàá wáyé, sọ pé àwọn kò tìí rí àwọn èròjà ìdìbò gbà láti olú ilé ẹgbẹ́ nàá tó wà ní ìlú Abuja.

Ó ní bíbá tí òun bá olórí ìgbìmọ̀ tó n mójútó ìdìbò abẹ́lé ní ìpínlẹ̀ Ogun, Alhaji Muhammed Idabawa, kò so èsò kankan, nítorí pé Idabawa nàá sọ pé omiinú n kọ òun nàá lórí bí èròjà ìdìbò kò ṣe tíì gúnlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ogun.

Bayii, Alaga APC ipinlẹ Ogun ti fidi ẹ mulẹ fun BBC pe ipinlẹ Ogun ti sun idibo abẹlẹ wọn siwaju nitori pe ilé ìyá ẹgbẹ ko gbe ohun elo ranṣẹ. O ni wọn yoo kede ọjọ tuntun to ba ya.

Kano:

Idibo ti bẹrẹ nibudo kọọkan nipinlẹ Kano bayii. Nigba ti awọn eeyan ti jade sibudo idibo mii ti wọn si n duro de awọn ohun eelo idibo kaakiri.

Àkọlé àwòrán,

Ganduje ko ni alatako kankan lati APC Kano

Gomina Ganduje Abdullahi Umar nikan lo jade lati tun dije tẹsiwaju lẹẹkan sii gẹgẹ bii gomina Kano.

Àkọlé àwòrán,

Ibo abẹlẹ APC ti bẹrẹ ni Kano

Bayii ibudo idibo bii Hotoro North, Unguwa Uku Cikin Gari àti Gyadi Gyadi ti n mu esi idibo wọn wa si Kano.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn obinrin Kano naa jade wa dibo abẹlẹ APC

Akọroyin BBC to wa ni Adamasingba ni ọpọ awọn oludibo lo ṣi wa nita abawọle papa iṣere naa ti wọn koi tii raaye wọle, bẹẹ, ko tii si oludije kankan to tii de.

Buhari borí ìdìbò abẹ́lẹ́ fun ìdíje ààrẹ̀ lẹgbe APC

Ìgbésẹ̀ ìdìbò abẹ́lẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣelu All Progressives Congress ki wọn fi yan awọn oludije ọmọ ẹgbẹ fun ipo gomina àti aarẹ fun idibo 2019.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan an ni ẹgbẹ APC dìbò yan Mohammadu Buhari gẹgẹ bi oludije kan ṣoṣo fun ipo aarẹ lọdun 2019.

Nipinlẹ Kano nikan ni Buhari ti ni o lé diẹ ni ọ̀rùn-dín-ni-miliọnu-mẹta ibo pe kó tésiwaju lẹẹkeji. Gomina Abdullahi Ganduje to ṣalakoso ibo naa ni Buhari ni 2,931,235 ìbò.

Bakan naa ni ọmọ ṣori nipinlẹ Katsina nibi ti Buhari ti ni ìbò 802, 819 ninu gbogbo awọn 813, 877 to forukọ silẹ.

Ẹrin kò yatọ nipinlẹ Rivers nibi ti Buhari ti ni ibo 388, 653 àti nipinlẹ Imo to ti ni 697, 532 ìbò ninu àwọn 944, 843 to forukọ silẹ titi lọ ba àwọn ipinlẹ bii Bauchi, Borno, Bayelsa. Sokoto àti Zamfara.

Eyi fihan pe Mohammadu Buhari ni gbogbo wọn ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti faramọ pe ko tun dije lorukọ ẹgbẹ sipo aarẹ ninu idibo Naijiria to m bọ lọdun 2019.

Ìdìbò abẹ́lẹ́ fún ìpo gomina yoo wáyé lóni

Idibo abẹle lati yan oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC yoo waye lawọn ipinlẹ to ku ni Naijiria loni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan an yatọ si ti ipinlẹ Imo ati ti Eko ti wọn sun si ọjọ kini, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Àkọlé fídíò,

NLC: Àwọn olósèlú ń la títì láì sanwó osù torí owó tí wọn yóò rí lórí àkànse isẹ́

APC gbe orukọ awọn oludije gomina jade

Igbimọ amusẹya fẹgbẹ oselu APC jake-jado Naijiria, ti gbe orukọ awọn oludije fun ipo gomina, ti wọn ti wẹ yan kain-kain lẹyin ayẹwo kinni-kinni labẹ ẹgbẹ oselu naa jade.

Atẹjade kan ti adele akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu APC, Yekini Nabena fisita, lo sisọ loju ọrọ yii.

Ni ẹkun iwọ oorun Guusu orilẹ-ede yii ati ilẹ Kaarọ Oojiire lapapọ, ipinlẹ mẹta ni pere ni ẹgbẹ oselu APC ti gbe orukọ awọn oludije gomina to pegede sita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọlọ́jọ́ festival 2018: Láwàní (ọ̀já) ni máa kọ́ka wé kí n tó jẹ Ọọni nítórí Oodua ló nií

Idi ni pe ninu awọn ipinlẹ mẹfa to wa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ipinlẹ mẹta pere lo ku ti yoo seto idibo gomina lọdun 2019. Awọn ipinlẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ, Ogun ati Eko.

Ẹwẹ, nipinlẹ Kwara, to jẹ ara ilẹ Oodua, ẹgbẹ oselu APC ṣẹṣẹ kede orukọ awọn eeyan to yege lati dije fun ipo gomina nibẹ.

Eeyan melo lo mọ to fẹ dije gomina ladugbo rẹ ?

Ipinlẹ EKo:

1.H.E. Akinwunmi Ambode - O yege2.Dr. Kadir Obafemi Hamzat - O yege (Bayii, o ti ju awà silẹ fun Jide Sanya-Olu, pe oun yọ̀ǹda ipinlẹ Eko fun Sanya-Olu lasiko yii)3.Jide Sanwo-OluCleared - O yege

Ipinlẹ Ọyọ:

1.Niyi Akintola, SAN - O yege

2.H.E. Christopher Alao Akala - O yege3.Joseph Olasunkanmi Tegbe - O yege4.Dr. Olusola Ayandele, PhD - O yege5.Dr. Owolabi Babalola - O yege6.Dr. Azeez Popoola Adeduntun - O yege7.Adebayo Adekola Adelabu - O yege8.Hon. Barr. Adebayo Shittu, Esq -Ko yege (ko ni iwe ẹri isinru ilu NYSC ni èyí to ti ni òun kò kọ̀ lati ṣẹṣẹ lọ sin ilẹ̀ baba oun lasiko yii)

Ipinlẹ Ogun:1.Jimi Lawall - O yege2.Dapo Abiodun - O yege3.Hon. Bimbo Abiodun - O yege4.H.E. Sen. Adegbenga Kaka - O yege5.Hon. Kunle Akinlade - O yege6.Abayomi Semako Koroto Hunye -O yege

Ipinlẹ Kwara1) Mal. Saliu Mustapha -Kò yege

2) Abdulfatai Yahaya Seriki -Kò yege

3) AbdulRaham AbdulRasak - Ò yege

4) Ọjọgbọn Ọba AbdulRaheem -Ò yege.

5) Mal. Ishaq Modibbo Kawu -Ò yege.

6) Hon. Kayode Omotoshe - Kò yege.

7) Yakub Gobir - Ò yege.

8) Mal. Lukman Olayiwola Mustapha -Ò yege

9) Shuaib Yahman Abdullahi -Ò yege

10) Moshood Mustapha -Ò yege

11) Dele Mohammed Belgore (SAN) - ó yọwọ́ pé òun kò ṣe mọ́.

12) Tajudeen Audu -ó yọwọ́ pé òun kò ṣe mọ́.

13) Hakeem Lawal -Ò yege

Awọn eeyan to yege yii, ti yoo kopa ninu idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC, to n bọ lọjọ Aiku ni yoo maa figa gbaga, ẹni ti odu rẹ ba si kun ju ninu wọn, ni yoo soju ipinlẹ rẹ pẹlu awọn oludije yoku latinu awọn ẹgbẹ oselu alatako lọdun 2019.

APC sún ìdìbò abẹ́lé fún ìpò gómìnà síwájú nipinlẹ Imo ati Eko

Ẹgbẹ oṣelu APC ti sun idibo abẹle fun ipo gomina ni Ipinlẹ Eko to yẹ ko waye lọjọ Aiku tẹlẹ si ọjọ Aje bayii.

Alaga gbogbo fun ẹgbẹ oṣelu naa Adam Oshiomole lo fi ọrọ lede lọjọ Abamẹta.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn oludije gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Eko tẹlẹ, Ọbafẹmi Hamzat ti yẹba fun Babajide Sanwo-Olu, saaju idibo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obafẹmi Hamzat Kadiri ni oun kò díje mọ sipo gomina ipinlẹ Eko

Dokita Kadri Ọbafemi Hamza, to kede igbesẹ rẹ yii fawọn Akọroyin ni pe oun ko ni dije mọ lati dupo gomina ipinlẹ Eko.

O wa rọ awọn alatilẹyin rẹ lati fọwọsowọpọ ri i pe Sanwo-Olu lo jawe olubori, ninu idibo abẹle naa ti yoo waye lọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu kẹwaa.

Ninu ọrọ rẹ, Femi Hamzat ni oun gbagbọ pe Sanwo-Olu ni okun ati agbara lati mu itẹsiwaju ba ipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, APC

Àkọlé àwòrán,

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe awọn eekan oloṣelu lẹgbẹ oṣelu naa kaakiri awọn ipinlẹ ni wọn pin eto idibo naa mọ ara wọn lọwọ

Hamzat fikun pe, itẹsiwaju ipinlẹ Eko pọn dandan ju ẹnikẹni lọ, nitorina ni oun se yẹba fun ẹnikeji oun ti awọn ti wa tipẹtipẹ.

Femi Hamzat wa parọwa si awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati fọwọsowọpọ, ki itẹsiwaju le ba ẹgbẹ naa.

Bó ṣe n lọ ni àwọn ipinlẹ tó kù

Awọn ipinlẹ yoku bii ipinlẹ Ekiti, Ondo ati Ọsun ti seto idibo gomina tiwọn, ti wọn ko si ni kopa ninu eto idibo gomina ti yoo waye lawọn ipionlẹ yoku lọ̀dun 2019.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Adebayo Shittu wà lára awọn to fẹ́ díje fun ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ

A gbọ pe ẹgbẹ oselu APC ni Shittu ko wẹ yan kain-kain lati kopa ninu idibo abẹle fawọn oludije fun ipo gomina naa, nitori pe ko seto isinru ilu lẹyin to jade nile ẹkọ fasiti, gẹgẹ bi ofin ilẹ wa se laa kalẹ.

Bẹẹ ba si gbagbe, Adebayọ Shittu gan ti sọ loju-taye pe, oun ko kopa ninu eto sinru ilu, nitori bi oun se jade fasiti, ni wọn dibo yan oun sile asofin ipinlẹ Ọyọ.

Ètò ìdìbò abẹ́lé kò tìí dábì pé yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Ogun. Àwọn ìròyìn kan sọ pé wọ́n ti sún ọjọ́ ìdìbò nàá síwájú nígbà tí àwọn kan tún sọ pé irọ́ ni. Alága ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Ogun, Olóyè Derin Adebiyi tó bá BBC sọ̀rọ̀ ní nkan bi i aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú tó yẹ kí ìdìbò nàá wáyé, sọ pé àwọn kò tìí rí àwọn èròjà ìdìbò gbà láti olú ilé ẹgbẹ́ nàá tó wà ní ìlú Abuja.

Ó ní bíbá tí òun bá olórí ìgbìmọ̀ tó n mójútó ìdìbò abẹ́lé ní ìpínlẹ̀ Ogun, Alhaji Muhammed Idabawa, kò so èsò kankan, nítorí pé Idabawa nàá sọ pé omiinú n kọ òun nàá lórí bí èròjà ìdìbò kò ṣe tíì gúnlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ogun.

APC supporters from all the 33 Local government arears of Oyo state are already gathered at Adamasingba Stadium, Ibadan, Oyo state capital for the governorship primaries. The supporters are standing in groups according to their LGAs, waiting for the accreditation to begin.