Omiṣore: Ọlọ́run mọ̀ sí bí mo ṣe fi PDP sílẹ̀

Iyiọla Omisore Image copyright Iyiola Omisore/Facebook
Àkọlé àwòrán Omiṣore ti kọ́kọ́ dupò gómìnà lábẹ́ àsìá PDP lọ́dún 2014

Igbákejì gómìnà ìpílẹ̀ Ọ̀ṣun nígbà kan rí, Sẹnatọ Iyiọla Omisore ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP sílẹ̀.

Omisore fi PDP sílẹ̀. O ni òun yóò lọ si íbi tó ti ní ìrètí láti díje dupò gómìnà nínú ètò ìdìbò gómìnà tí yòó wáyé lọ́jọ́ kejìlélógún, oṣù Kẹsàn án.

Omiṣore kéde ìgbésẹ̀ nàá nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta fún àwọn àkọ̀ròyìn ní ìlú Oṣogbo, tí ṣe òlú ìlú fún ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. ni iwo oorun guusu Nàìjíríà.

Ó ní ''nínú ẹgbẹ́ tuntun tí maa fẹ́ darapọ̀ mọ́ ni àfojúsùn mi yóò ti wá sí ìmúṣẹ, àti pé mo ti ṣetán láti dóòlà ìpínlẹ̀ nàá kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso APC."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní èyí ló fà á tí òun fi ń wá ẹgbẹ́ mì í tí yóò fàáyè gba òtítọ́ àti àwọn tó tọ́ láti dòólà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kúrò ní abẹ́ ìṣèjọba tó n ṣe é bí kò ṣe tọ́, tí yòó sí mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn ara ìlú láti jèrè ìjọ́ba tó n kó àkóyawọ́.

Ẹ̀wẹ̀, Omisore ní ''mo ti kúrò ní PDP, láì fi ti akitiyan mi láti kọ́ ẹgbẹ́ nàá se, lẹ́yìn tí mo ti fi ọ̀rọ̀ nàá lọ Ọlọ́run mi, ìdìlé mi, tó fi mọ́ àwọn alátìlẹyìn mi ní tilé-toko, ki n to bọ́ sí ẹgbẹ́ tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìbára ẹni dọ́gba, tó fi mọ́ ifẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó múná dóko hàn.