Bàbá olówó Chelsea, Abramovich rí ìdíwọ́ lórí ìwé ìgbéèlú ilẹ́ Gẹ̀ẹ́sì

Roman Abramovich

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Iroyin sọ wi pe asẹ iwe igbelu rẹ dọpin ni bii ọsẹ mẹta sẹyin

Ẹni to ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Roman Abramovich ti koju idiwọ lori a ti gba iwe igbelu fun ilẹ Gẹẹsi.

Abramovich to jẹ ọmọ orilẹede Russia ni ko si nibi asekagba idije FA to waye lọjọ Abamẹta, nibi ti Chelsea ti gba ife naa lẹyin ti wọn naa Manchester United pẹlu àmìn ayo kan si òdo.

Ọmọ ọdun mọkanlelaadọta naa ni wọn sọ wi pe ati gba iwe igbelu rẹ n gba ọjọ gbọọrọ ju bi oti yẹ lọ.

Bi o ti lẹ jẹ wi pe ile isẹ arakunrin naa ko ti fesi si isẹlẹ naa, iroyin sọ wi pe àṣẹ iwe igbelu re dopin ni bii ọsẹ mẹta sẹyin.