Grenfell Tower: Ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ lórí ilé alájà tó jóná ní London

Grenfell tower

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́ yìí láti fún wọn lánfàní láti jẹ́rìí sí ohun tí wọn mọ

Ẹlẹ́dẹ̀ yóò dé Ọ̀yọ́, ariwo rẹ̀ ní yóò pọ̀. Láìpẹ́, ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ lórí ilé alájà tó jóná ní London.

Àwọn ìdílé tó pàdánù àwọn ènìyàn wọn níbi ilé alájà mẹ́rìlélógún ti Grenfell Tower tó jóná ní Keshinton, west London yóò rí ìdájọ́ fún àwọn ẹni wọn to pàdánu ẹ̀mí níbẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Òsẹ̀ méjì ní o yẹ kí ètò ìwádìí òhún lò tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì sọ̀rọ̀ bó ṣe wùú láì fi gbèdéke síi ibi tí wọn le sọ̀rọ̀ mọ

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́ yìí láti fún wọn lánfàní láti jẹ́rìí sí ohun tí wọn mọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀ àwọn tí yóò kópa ní wọn nírètí pé yóò ka ọ̀rọ̀ tàbí sàfihàn fọ́rán-án àwọn olólùfẹ́ wọn tó ti kú.

Òsẹ̀ méjì ní o yẹ kí ètò ìwádìí òhún lò tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì sọ̀rọ̀ bó ṣe wùú láì fi gbèdéke síi ibi tí wọn le sọ̀rọ̀ mọ

Ìwádìí ọ̀hún yóò sàyẹ̀wò sí ikú ènìyàn méjìléláàdọ́rin, tó fi mọ́ ọ́kan lára wọn tó wà ní ilé ìwòsàn láti inú oṣù kẹfà ọdún 2017, to ṣẹ̀ṣẹ̀ saláìsí nínú oṣu kíní ọdún yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọmọọba Harry ati Meghan Markle ti di tọkọtaya

Àkọlé fídíò,

Àjọ ọlọ́pàá: kọ́kọ́ sàyẹ̀wò ọlọ́pàá kó tó yẹ̀ ọ́ wò

Ọ̀pọ̀ àwọn tí yóò kópa ní wọn nírètí pé yóò ka ọ̀rọ̀ tàbí sàfihàn fọ́rán-án àwọn olólùfẹ́ wọn tó ti kú.

Orúkọ gbogbo àwọn tó ti saláìsí ní wọn ò kà síta nibi ìgbẹ́jọ́ tí yóò wáyé ní ilé ìgbáfẹ́ Millennium Gloucester, ní Gúúsù Kensington, west London, sùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ebí ní yóò lánfàní láti sọ̀rọ̀ níbẹ̀

Sir Martin Moore-Bick tó jẹ́ adájọ́ fẹ̀yìntí ni yóò jẹ́ alága ìwádìí, tí yóò sì máa gba ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́dani, àwọn ilé-iṣẹ́ àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.