Àṣírí fàyàwọ́ ọmọnìyàn tú nílé ẹ̀kọ́ kan nípìlẹ́ Edo

awon Akekoo
Àkọlé àwòrán,

Okoduwa wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ òhún láti kíyèsára kí wọn máà bọ́ sọ́wọ́ ìtànjẹ àwọn fàyàwọ̀ ọmọnìyàn

Ó tí tó ọmọ ọgọ́rùn ún tí àwọn fàyàwọ̀ ọmọnìyàn ti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Libya láti ilé ìwé kan ní ìlú Benin, ní ìpínlẹ̀ Edo, orílẹ̀-èdè Nàìjíárìà láti bíi oṣù mẹ́rin sẹ́yìn.

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki lórí ìfàyàwọ́ ọmọnìyàn àti ìrìnàjò kúrò nílùú lọ́nà àìtọ́, Solomon Okoduwa, sọ pé, ọ̀gá kan nílé ẹ̀kọ́ náà ló sọ bẹ́ẹ̀ fún òun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ní àwọn fàyàwọ́ ọmọnìyàn ti kojú bọ ilé ìwé òhún láti máa kó àwọn ọmọ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.

Ọ̀gbẹ́ni Okoduwa sọ̀rọ̀ òhún ní ìlú Benin lásìkò tí wọn ń ṣe ìpolongo ìta gbangba kan

Àkọlé fídíò,

Àṣírí ìfàyàwọ́ ọmọnìyàn tú nílé ẹ̀ka kan nípìlẹ́ Edo

Ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ Edo kò ní fààyè gba irú ìwà búburú báyìí láti tèsíwájú nípìnlẹ̀ náà

O ni ìjọba yóò fí irú nkan báyìí kún àwọn ìpolongo ìta gbangba tí wọn ń ṣe kí àwọn ará ìlú leè dẹ́kún fàyàwọ́ ọmọnìyàn, àti pé àjọ ìjọba tó ń rí sí gbígbígun ti fàyàwọ́ yóo máa tọ pinpin àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ọ̀hún.

Okoduwa wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ òhún láti kíyèsára kí wọn máà bọ́ sọ́wọ́ ìtànjẹ àwọn fàyàwọ̀ ọmọnìyàn láti rínrin àjò to léwu nínú lilọ sí orílẹ̀-èdè Libya