Àwẹ̀ Ramadan wákàtí 22 lóòjọ́, ṣé ẹ̀mí rẹ gbà á?

Aworan alaawe to'n duro de asiko iṣinu
Àkọlé àwòrán,

Wákàtí a má jó bi pé kò sáré rárá nínú àwẹ̀.

Lootọ ní pé láàrin ìgbà tí oòrùn bá yọ sì ìgbà tí o bá wọ ní jíjẹ àti mímú dì èèwò fún àwọn Mùsùlùmí nínú oṣù Ramadan.

Ṣùgbọ́n bí ojú ọjọ ti ṣe rí a má ṣe òkùnfà ìyè wákàtí ti awọn èèyàn fi n gba àwẹ ní àwọn orílẹ̀èdè àgbáyé.

Láwọn orílèèdè kàn, ìyè wákàtí àwẹ̀ ko kọjá àfaradà ṣugbọn láwọn ibòmìíràn,a máa dàbí pé àwẹ̀ ò ní tán.

Ní ìgbà wọ̀nyí, àwẹ̀ gbígbà a máa dàbí àdánwò àti ìpèníjà fún àwọn mùsùlùmí tí wọ́n gba àwẹ̀ fún wákàtí pípẹ́.

Àkọlé àwòrán,

Wákàtí àwẹ̀ káàkiri àgbáyé

Àgbègbè àwẹ̀ ọlọjọgbòòrò

Ki a kọkọ fi ìbéèrè ṣọwọ́ pe ṣe ẹ mọ ìbí ti wọn n pé ní Greenland?

Greenland ni erékùsù ti o tobi jù lọ lágbayé.

Bi Ọlọ́run bá kọ ọ́ pé èèyàn ba wọn gba awẹ níbẹ̀, wákàtí méjìlelogun gbáko ní èèyàn o fí mẹnu mọ fún jíjẹ àti mímú.

Ìtumọ̀ eléyìí ni pé wákàtí meji péré ni yóò fi ṣínú, kí irun Maghrib ati Ishai ti yóò sì tún jẹ saari nínú rè!

Àkọlé àwòrán,

T'ọmọdé tí agbà ló má n ṣé isẹ́ ibadah oríṣiríṣi nínú oṣù Ramadan

Ẹyonda mi "sir"

Oṣiṣẹ ilera nílu Abuja ni Ọgbẹni Jimoh Jeleel Anjọrin.

Ìṣẹ rẹ̀ a sì máà gbà àgbàrá láti ṣe.

O sọ pé àwẹ̀ gbígbà fún wákàtí méjìlelogun kìí ṣe òun tó rọrùn ṣùgbọ́n tó bá jẹ pé àgbègbè náà ní Ọlọrun dá èèyàn sí, ''o di dandan láti gbà àwẹ̀ náà''

Lọdọ ti rẹ, Lateefat aya Ahmad ni t'oba se agbègbè bi Greenland loun ba wa,òun yóò gba àwẹ̀ náà lai bikita.

''Ati ẹni tó gba wákàtí meji ati ẹ́ni to gba wákàtí méjìlelogun kò sí eyi tó rọrùn láti gbà. A fí kí ọlọrun fún wà ní òkun àti agbára láti gbà níí''

Àwọn orílèèdè míràn tí wọ́n n gbà àwẹ̀ fún wákàtí to pé ni

  • Russia àti Iceland wákàtí ogún
  • Canada wákàtí metadinlogun
  • Amerika wákàtí mẹẹdogun sí metadinlogun

Nàìjíríà àti àwọn orílè-èdè bi Kenya n gbádùn lafiwe pẹlú àwọn tá ká ṣáájú.

Wákàtí mẹ́rìnlá làwẹ̀ gbígbà ni Nàìjíríà,Kenya wákàtí mẹ́tàlá, Egypt si jẹ́ wákàtí mẹẹdogun.

Ṣùgbọ́n awọn tí ìyè wákàtí àwẹ̀ wọn kéré diẹ ni Australia ati Chile níbi tí wọn ti n gbà àwẹ̀ wákàtí mọkanla ati mẹwàá.