Abikẹ Dabiri: irọ́ ni wọ́n ń pa f'awọn ọ̀dọ́ pé wọn a ríṣẹ́ ṣe

Àkọlé fídíò,

Abikẹ Dabiri: Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ Naptin àti àwọn aṣọ́bodè Nàìjíríà

Ọmọ Nàìjíríà mẹrindínlógún ni wọn ti fẹ̀sùn kàn ni Paris pé wọn ń f'awọn ènìyàn ṣiṣẹ́ aṣẹwo ni France, Italy ati Spain.

Ọkùnrin marun un àti obìnrin mọkanla ni àjọ arannilọwọ ti kìí ṣe tijọba, Bus De Femme, ti gbe lọ sile ẹjọ ni France.

Àjọ yii gba agbẹjọ́rò fún àwón ọmọ Naìjíríà ti wọn fi tipá mu fi ṣe iṣẹ́ aṣẹwó nilẹ̀ Yuroopu.

Igbẹjọ fihan pé àwọn oniṣẹ ibi yii maa n parọ fun awọn ènìyàn pe wọn ń kó wọn lọ ṣiṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀, iṣẹ́ agbálẹ̀, iṣẹ́ iná dida ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Abikẹ Dabiri, to jẹ oluranlọwọ pàtàkì fún Aarẹ lori àjọṣepọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ati ọrọ àwọn ènìyàn Nàìjíríà loke òkun, gba àwọn òbí àti alagbatọ nimọran láti mojuto àwọn ọmọ wọn.

O ni ki wọn má jẹ ki ẹnikẹni fi iṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè tàn wọ́n jẹ́ mọ́ nitori pe irọ ni.

O rọ àjọ NAPTIN àti àwọn aṣọ́bodè láti tẹra mọ́ iṣẹ takuntakun ti wọn ń ṣe, ki àwọn àjọ arannilọwọ gbogbo fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati fi gbogun ti àwọn oníṣẹ ibi to ń ta ènìyàn sóko ẹrú kaakiri agbaye.

Abikẹ Dabiri fidunnu hàn pe bi ọwọ́ ṣe ń tẹ̀ àwọn ìka yii nile naa ni wọn ń mú wọn loke okun fun ìjìyà to tọ́.

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹ́ aṣẹ́wó àti gbígbé oògùn olóró ni wọn ń fi ọ̀dọ́ Nàìjíríà ṣe lókè òkun

Ọjọ kẹrinla oṣu karun un ni wọn kọkọ gbọ́ ẹjọ́ náà nile ẹjọ giga ti Paris ki adajọ to sọ àwọn mẹrin ninu wọn sẹwọn.

Awọn mokandinlaadọta ni wọn padà jẹri lodi si àwọn Authentic Sisters ti wọn fẹsun kàn pé wọn parọ fún àwọn pe iṣẹ ń duro de wọn ni Paris.

Awọn olùpẹ̀jọ́ mẹjọ akọ́kọ́ ti àjọ Bus De Femme, gba agbẹjọro fun náà ṣalaye pé àwọn ọbayejẹ ọ̀hún mu àwọn lọ sile babalawo lati búra pé àwọn kò ni dà wọn tabi ki wọn kóbá wọn ti wọn ba de ilẹ̀ Yuroopu tán.

Wọn ni àwọn ìkà ènìyàn yii a tún gba owó ti àwọn ba pa lẹ́nu iṣẹ́ aṣẹwo ọ̀hun lọwọ wọn.

Ajọ arannilọwọ yii tún n ṣeto itọju fun àwọn ènìyaǹ naa nile iwosan bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Asa Trokosi nibi ti ọmọde ti n jiyan ẹsẹ mọlẹbi rẹ , wọpọ ni Ghana, Togo ati Benin.

Àkọlé àwòrán,

Ki gbogbo òbí àti alágbàtọ́ máa ṣọ àwọn ọmọ wọn