Offa robbery: Saraki, NOPRIN ní ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ ṣàlàyé bí Adikwu ṣe kú

Adikwu, Olórí ikọ̀ adigunjalè tó ṣ'ọṣẹ́ ní Ọ̀ffà

Oríṣun àwòrán, NIGERIAP POLICE FORCE

Àkọlé àwòrán,

Awọn marun un ni awọn afurasi ti o farahan ni iwaju ile ẹjọ nilu Ilọrin ni ọjọru.

Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba Bukola Saraki ati àjọ ti o n pè fun atunṣe ileeṣẹ ọlọpaa (NOPRIN) ti pe fun iwadi si bi Michael Adikwu, to jẹ olori awọn afunrasi ọlọṣa ti wọn ja ọpọ banki lole ni ilu Ọffa ni oṣu kẹrin, ọdun 2018, ṣe ku si ihamọ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ Yusuph Olaniyonu fọwọ si, Saraki ke pe ileeṣẹ aarẹ lati gbe igbimọ dide lati ṣe iwadii na. NOPRIN naa sọ ninu atẹjade adari ajọ naa pe o fi han pe ootọ ni pe awọn ọlọpaa ti pa Adikwu si ihamọ bo tilẹ jẹ pe o ni oriṣiriṣi ọrọ lati sọ fun ile ẹjọ.

Gẹgẹ bi ọrọ ti agbẹjẹro agba ni ipinlẹ Kwara, Kamaldeen Ajibade, sọ niwaju ile ẹjọ lọjọru ni ilu Ilọrin, ọga ọlọpaa ikọ to ṣe iwaadi idigunjale naa, Abba Kyari lo fi to oun leti pe Adikwu ti ku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adikwu, to figba kan jẹ ọlọpaa ri ki iṣẹ to bọ lọwọ rẹ lo ko awọn adigunjale to ṣọṣẹ ni ilu Ọffa sodi.

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force

Àkọlé àwòrán,

Olórí ikọ̀ adigunjalè tó ṣ'ọṣẹ́ ní Ọ̀ffà ti kú

Banki marun un ni awọn adigunjale naa kọlu nigba naa ti wọn si pa eeyan ti ko din ni ọgbọn ninu eyi ti awọn ọlọpaa wa.

Awọn afurasi marun un ti wọn farahan niwaju ile ọjọ loni ni Ayoade Akinnibosun, Ibikunle Ogunleye, Adeola Abraham, Salaudeen Azeez ati Niyi Ogundiran.

Amọṣa adajọ ti o n gbọ ẹjọ naa, Halima Salman, ti sun igbẹjọ di ọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2018 lati fun olupẹjọ lanfani ati ṣe awọn atunṣe to yẹ lori iwe ipẹjọ wọn.

Nigba ti BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa lati bere bi o ṣe kú ni agbẹnusọ wọn ni ile ẹjọ nikan lo le ṣalaye.

Ọwọ́ ṣìnkú ọlọ́pàá tẹ àwọn adigunjalè apanìyàn Ọffa mìíràn

Oríṣun àwòrán, PRNigeria

Àkọlé àwòrán,

Ojú olè rèé!!!!!!

Awọn ọlọ́pàá ti mu àwọn ole ti won ja ni Ọffa ti wọn ṣe ikú pa ọpọlọpọ ènìyàn.

Awọn ọlọ́pàá fi aworan àwọn olè naa sita ninu ẹrọ ayelujara pẹlu ileri owo miliọnu marun un naira fun ẹnikẹni to ba kẹfin wọn nigboro tẹlẹ.

Alukoro ọlọ́pàá ni àwọn oninure eniyan ti ń pe wọn fun itọni si awọn ole naa kaakiri ni eyi to ti ń bi èso rere bayii.

Bayii, ikọ̀ IRT ti ọga ọlọ́pàá gbe lọ si ipinle Ekiti, Kwara, Oṣun, Oyọ àti Ondo ti mu meji ninu àwon ìgárá ọlọ́ṣà náà.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Awọn olè náà ni:

  • Kunle Ogunlẹyẹ ti àpèjà rẹ ń jẹ Arrow. O jẹ ọmọ ọdun marundinlogoji. Owọ ọlọ́pàá tẹ̀ẹ́ ni Oró nipinlẹ Kwara lana. ọmọ ipinlẹ Kwara naa ni o jẹ.
  • Michael Adikwu ni ẹni keji ti ọwọ́ tẹ̀. O jé ọmọ bibi ijọba ibilẹ Apa nipinlẹ Benue. Wọn ti lee lẹnu iṣẹ́ ọlọ́pàá tẹlẹ lọdun 2012 nitori pe, o pàdí àpò pẹlu awọn adigunjale ni Kwara ki wọn to fi sẹwọn di ọdun 2015.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade ti awon ọlọpaa fi sita ni pe Adikwu di ọlọ́ṣà ni kete to jade kuro ni ẹwọn. Osẹ meji sẹyin ni awọn agbofinro IRT tun mu u ni ipinle Kwara.

Gbogbo àwọn afurasi ati awọn ti ọwọ agbofinro ti tẹ̀ ni wọn ti n ran àwon ọlọpaa lọwọ lati mu àwọn to kù wọn.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE

Àkọlé àwòrán,

Awọn afurasí náà gbẹ̀mi ogunlọ́gọ̀ ènìyàn pẹ̀lú ọlọ́pàá mẹsan

Alukoro ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori idigunjale Ọffa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn adigunjalè míràn ti ọwọ́ tún tẹ̀