Èèmọ̀, alukoro PDP tẹ́lẹ̀, Olisah Metuh dákú ní ilé ẹjọ́

Olisah Metuh

Oríṣun àwòrán, Pdp

Àkọlé àwòrán,

Metuh ń jẹ́jọ́ fún ẹ̀sùn ṣíse owó ìlú báṣu-bàṣu

Alukoro nigba kan ri fun ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹ-ede Naijiria, Olisa Metuh, daku ni nu ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja loni.

Ọgbẹni Metuh ati ileeṣẹ rẹ kan n kawọ pọnyin rojọ fun ẹsun gbigba irinwo miliọnu Naira lọna àìtọ́ lati ọfiisi olootu aabo lorilẹ-ede yii lọdun 2014.

Metuh ṣubu lulẹ nigba ti wọn pe ẹjọ rẹ ni ọjọ Aje.

Ni kia ni adajọ to n gbọ ẹjọ naa pe awọn oṣiṣẹ ilera wọle lati wa moju to o ti o si gbe ẹjọ naa ti sẹgbẹ kan ki wọn fi mojuto o.

Nigba ti adajọ tun fẹ pe ẹjọ naa lẹyin ti wọn da Metuh pada saye, agbẹjọro rẹ faake kọri pe ko le ṣeeṣe nitori ẹmi onibara oun lo ṣe iyebiye ju fun oun.

Ẹjọ rẹ ni onidajọ Okon Abang, kọkọ pe lati tẹsiwaju ninu igbẹjọ ẹsun ṣiṣowo ilu baṣubaṣu ti wọn fi n kan an.

Onidajọ Abang ti wa sun igbẹjọ si ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejileogun, oṣu karun un ọdun yii.