Ramadan, wakati ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kini ẹ mọ̀ nipa àwọn Yollywood?
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Ọwọ́ ṣìnkú ọlọ́pàá tẹ àwọn adigunjalè apanìyàn Ọfa míràn.
Ojú olè rèé!!!!!!
Awọn ọlọ́pàá ti mu àwọn ole ti won jalè ni Ọfa ti wọn ṣe ikú pa ọpọlọpọ ènìyàn.
Awọn ọlọ́pàá fi aworan àwọn olè naa sita ninu ẹrọ ayelujara pẹlu ileri owo miliọnu marun un naira fun ẹnikẹni to ba kẹfin wọn nigboro tẹlẹ.
Bayii, ikọ̀ IRT ti ọga ọlọ́pàá gbe lọ si ipinle Ekiti, Kwara, Oṣun, Oyọ àti Ondo ti mu meji ninu àwon ìgárá ọlọ́ṣà náà.
Abikẹ Dabiri: irọ́ ni wọ́n ń pa f'awọn ọ̀dọ́ pé wọn a ríṣẹ́ ṣe
Abikẹ Dabiri: Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ Naptin àti àwọn aṣọ́bodè Nàìjíríà
Ọmọ Nàìjíríà mẹrindínlógún ni wọn ti fẹ̀sùn kàn ni Paris pé wọn ń f'awọn ènìyàn ṣiṣẹ́ aṣẹwo ni France, Italy ati Spain.
Ọkùnrin marun un àti obìnrin mọkanla ni àjọ arannilọwọ ti kìí ṣe tijọba, Bus De Femme, ti gbe lọ sile ẹjọ ni France.
Àjọ yii gba agbẹjọ́rò fún àwón ọmọ Naìjíríà ti wọn fi tipá mu fi ṣe iṣẹ́ aṣẹwó nilẹ̀ Yuroopu. E ka ekunrere re ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Àsá Trokosi tó ń fi ọmo jìyà ẹ̀sẹ̀ mọ̀lẹ́bi rẹ̀, wọ́pọ̀ ní Ghana, Togo àti Benin.
Asa Trokosi nibi ti ọmọde ti n jiyan ẹsẹ mọlẹbi rẹ , wọpọ ni Ghana, Togo ati Benin.