Boss Mustapha: A na 64 mílìònù náírà fun àtúntò ójú òpó ayélujára

Aworan Boss Mustapha
Àkọlé àwòrán,

O ní àṣeyọrí tó ṣe pàtàkì jùlọ ní pé àwọn ará ìlú yóò ní ore-ọ̀fẹ́ láti dásí ìṣèjọba níbikibi tí wọn bá wà

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni awọn tí mú àtúntò bá ojú òpó ayélujára ilé iṣẹ́ akọwé àgbà ìjọba pẹ̀lú mílìònù mẹ́rìnlélọ́gọ́ta Náìrà.

Akọ̀wé àgbà fún ìjọba Boss Mustapha, ló kédé ọ̀rọ̀ ọ̀hún lánàá lásìkò tí wọn ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀.

Boss sàlàyé pé ìgbésẹ̀ yíì ṣe pàtàkì lójúnà àti mú kí gbogbo ènìyàn dá sí ètò ìjọba pàápàá lórí ayélujára.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ní àṣeyọrí tó ṣe pàtàkì jù lọ ní pé àwọn ará ìlú yóò ní ore-ọ̀fẹ́ láti dásí ìṣèjọba níbikibi tí wọn bá wà.

Sugbon ọro naa ti mu iriwisi orisirisi dani lodo awọn ara ilu lori Twitter.

Lati odun 2017 ni won ti gbe ise atunto ojo opo naa fun agbasese.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Mustapha ní mílìònù mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ọ̀hun yóò mójútó ètò ikọ́ni awọn oṣìṣẹ́ àti pípesè àwọn ẹ́rọ Kọ̀mpútà.

Mustapha sàlàyé pé lára àwọn ohun amóríwú tó wà lóri ojú òpó ayélujára náà ni gbogbo àwọn ìwé ìjábọ̀ àwọn ìgbìmọ aláṣẹ láti ọdún 2015 yóò wà lórí rẹ̀, àwọn ìwé àdéhùn pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ìlúòkèrè

O ni mílìònù mẹ́rìlélọ́gọ́ta òhun yóò mójútó ètò ikọ́ni àwọn oṣìṣẹ́ àti pípìsè àwọn ẹ́rọ Kọ̀mpútà.