Afẹ́nifẹ́re: A kò tíì ní ẹnìkankan táá gbè lẹ́yìn rẹ̀ fún ipò Ààrẹ

Aworan Obasanjoa ati awọn ọmọ ẹgbẹ afenifere

Oríṣun àwòrán, @SenatorAdesanya

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin ipade naa Afẹ́nifére kọ lati sọ ẹni ti wọn yoo mu laarin Buhari ati Atiku

Ori la fi n mẹran lawo sugbọn to ba kan ọrọ yiyan ẹni ti awọn Yoruba yoo gbe lẹyin rẹ́ fun ipo Aarẹ Naijiria lọdun 2019, ọrọ naa yoo gba isiro ati apero daadaa.

Eyi lo mu ki ẹgbẹ́ Afẹnifẹre maa ti sọ pato ẹni ti wọn yoo gbe lẹyin rẹ fun idibo Aarẹ ọdun 2019.

Laipẹ yi ni ẹgbẹ naa se abẹwo si Ààrẹ àná lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà Oluṣegun Obasanjọ lati fọrọ jomitooro ọrọ lori odo ti awọn Yoruba yoo dọra si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọbasanjọ lo fa Ya'Adua àti Jonathan Kalẹ, o yan Buhari pẹlú

Abajade ipade naa ko ti tọka boya wọn fẹ se ti Buhari tabi ti Atiku sugbọn ipade naa tubọ fi ifarajin ẹgbẹ afẹnifẹre lori ọrọ aato isejọba ti ọpọ mọ si ''Restructuring.''

Afẹnifẹrẹ ko sẹsẹ maa tẹnu mọ atunto isejọba gẹgẹ bi ohun to le dẹkun wahala to n koju orilẹede Naijiria .

Àkọlé fídíò,

Atunto lo le yanju ọrọ Naijiria

Sugbọn loju opo ayelujara awọn eeyan ti dari ọrọ ipade naa si ibo miran.

Ohun ti wọn n sọ bayi ni pe se Afẹnifere lasẹ lati sọ ibi ti awọn Yoruba yoo lọ lọdun 2019.

Adebambo Olugbemigun n se kayefi lori bi o ti se jẹ Obasanjọ ni Afẹnifẹre lo ba ki wọn to le sọ ẹni ti wọ́n yoo gbaruku ti fun ipo Aarẹ lọ́dun 2019

Ero ọkan Adebambo se rẹgi pẹlu ti Abiodun Bamiduro

Ko jẹ tuntun mọ pe Atiku Abubakar ati Muhammadu Buhari ni wọn jẹ oludije to lewaju lati du ipo Aarẹ lọdun 2019.

Lati igba ti Atiku ti pegede si ni iriwisi ọtọọtọ ti n waye lori ẹrongba rẹ ati boya awọn ọmọ Naijiria yoo gba lati fi Atiku rọpo Buhari ni ile ijọba.

Ti a ko ba gbagbe ,Ààrẹ àná lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà Oluṣegun Obasanjọ ti saaju sàbẹ̀wò sí adarí ẹgbẹ́ Afenifere, Pa. Reuben Fasoranti ní ìlú Akure, tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo.

Nibi ipade naa Obasanjo sọ pé òhún gùn lé ìrìnàjò ọ̀hún láti gba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progress Congress (APC) lọdún 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìbẹ̀wò ọ̀hún jẹ́ ìgbà àkọ́kọ̀ sí adarí Afẹnifẹre láti ogun ọdún sẹ́yìn.

Kíni àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ń sọ lórí àwọn tí Obasanjọ ti yàn tẹ́lẹ̀

Àkọlé fídíò,

Kínì ìdí tí Obasanjọ fí sàbẹ̀wò sí adarí Afẹ́nifére

Àkọlé fídíò,

Kínì ìdí tí Obasanjọ fí sàbẹ̀wò sí adarí Afẹ́nifére

Ó gbóríyìn fún Afẹnifẹre fún àdúrótì, ìgbàgbọ́ nínú Yorùbá àtí ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Bákannáà, ni Fasoranti dúpẹ́ lọ́wọ́ Obasanjọ fún ìgbìyánjú rẹ̀ láti mú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dé èbúté ogo, o fi ẹ̀dùn ọkan rẹ hàn sí bí wọn ṣe ń darí rẹ̀.

Fasoranti ní àwọn wà lẹ́yìn PDP, SDP àti ADC.

Otunba Oyewole Fasawe àti Ayọ Osuntokun ni wọn jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ síbẹ̀