Buhari: Níbo ni iná ọba tí Ọbasanjọ́ ya $16bn lé lórí wà ?

Buhari ati Ọbasanjọ nki ara wọn
Àkọlé àwòrán,

Ọbasanjọ ti kọ lẹta si Buhari eleyi to di gbajugbaja kaakiri agbaye

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ wi pe Aarẹ tẹlẹri, Olusegun Ọbasanjọ ni ẹjọ lati ro, lori bi ijọba rẹ se na owo to le ni trilionu marun naira ($16 billion) lori ina mọnamọna lasiko rẹ.

Aarẹ Buhari sọ eleyii ni Ọjọ Isẹgun, ni Aso Rock ni Abuja, nigba to n gbalejo awọn ẹgbẹ to n satilẹyin fun Aarẹ Buhari, ti Ọga Agba Ileẹsẹ asọbode orilẹede Naijira, Hameed Ali, se adari fun.

Bi o ti le se wipe, aarẹ naa ko darukọ Ọbasanjọ, Amọ Aare Buhari so wi pe ‘ni bo ni ipese ina mọnamọna ti aarẹ tẹlẹri naa sọ wi pe oun na iye owo to to biliọnu mẹrindinlogun dọla naa wa?’

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ti a ko ba gbagbe, isẹ ipese ina mọnamọna ni isejọba Aarẹ Ọbasanjọ lọdun (1999-2006) da owo le lasiko, sugbọn ti awọn ajafẹto omoniyan, Serap sọ wi pe, wọn se basubasu.

Serap si kan si olootu eto idajọ lorilẹede Naijiria, Walter Onnoghen, lati se ofin toto bi wọn se naa owo naa.