Koko iroyin: Àyẹ̀wò di ọ̀ranyàn ni sọọsi, Ẹ̀mí èṣù ni okunfa ipààyàn Benue
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Ìjọ Redeem: Àyẹ̀wò ojú ara wà láti dènà ìjà nínú ìgbeyàwó
Oríṣun àwòrán, @PastorFOdesola
Ìgbésẹ̀ náà ló wà láti dènà ọ̀pọ̀ lààsígbò ló ń mi ìgbeyàwó lògbò-lògbò
Ìjọ Ìràpadà ti ẹ̀mi, táa mọ̀ sí The Redeemed Chriatian Church of God (RCCG) ti fi àtẹ̀jáde tuntun kan síta.
Atẹjade naa wi pé, láti àkókò yìí lọ, àwọn àfẹ́sọ́nà tó bá fẹ́ se ìgbeyàwó nínú ìjọ náà, ni wọn yóó máa se àyẹ̀wò fúń ṣáájú ìgbeyàwó lórí àwọn ohun to so rọ̀ mọ́ ìbálòpọ̀ àti ìbímọ wọn.
Buhari: Ìwà èṣù pátápátá ni ìkọlù àti ìpànìyàn nípínlẹ̀ Benue
Oríṣun àwòrán, Benue state government
Ẹni to ba n pa eeyan ti sọ alaafia rẹ nu, o si ti di ẹni itanu ati ẹni ifib
Aarẹ Muhammadu Buhari ni ẹmi esu lo n gbe inu awọn to n pa eeyan ni ipinlẹ Benue.
Aarẹ woye ọrọ yii ninu ọrọ ibanikẹdun to fi ranṣẹ si ibi isinku awọn fada meji atawọn ọmọ ijọ mẹtadinlogun, ti awọn afunrasi apaniyan kan ṣekupa nipinlẹ Benue.
Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, lo ṣoju fun aarẹ Muhammadu Buhari nibi eto isinku naa.E ka ekunrere re ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Ìtakurọ̀sọ máa ń jẹ́ kí ìsọ̀ ìwé ìròyìn dùn
Ìsọ̀ oníwe ìròyìn àtàwọn tó ń kà a lọ́fẹ̀ẹ́