NASS: San 2 Mílíọ́nù tàbí lọ ẹ̀wọ̀n ọdún méjì fún ìlòkulò Codeine

Aworan eni to n mu coedine
Àkọlé àwòrán,

Àbádòfin òhún ń wá ojúùtú sí òfin ìjọba Nàíjíríà (2004) tó de Oúnjẹ, àti àwọn ǹkan tó jọ mọ́ òògùn,

Ilé ìgbìmọ Aṣòfin Nàíjíríà tí buwọ́ lu àtúnṣe àbádòfin lorí ìlòkulò Tramadol tàbí òògùn ikọ́ olómi codeine pẹ̀lú àbá pé ẹni tí igbá ọ̀rọ̀ náà bá ṣí mọ́ lórí yóò fi ẹ̀wọn ọdún méjì jura tàbí kó san mílíónù méjì náìrà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àbádòfin ọ̀hún ń wá ojúùtú sí òfin ìjọba Nàíjíríà ti ọdún 2004 tó de oúnjẹ, àti àwọn ǹkan tó jọ mọ́ òògùn,

Òfin náà tí Betty Apiafi ( PDP Rivers) ṣe onígbọ̀wọ́ fún tún ń wá àtúnṣe sí ìjìyà tí yóò ṣe é gbọ́ nílé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀

Àbádòfin òhun ṣe àlàkalẹ̀ ìjìyà ẹnìkọ̀ọ̀kan láti orí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà, ẹ́wọ̀n ọdún méjì tàbí owó ìtanran àti ẹ̀wọ̀n papọ, tí ilé-iṣẹ́ àti gbogbo àwọn lọ́ọ̀gálọ́ọ̀gá ibẹ̀ yóò jẹbi ẹ̀sùn gẹgẹ bíi pé àwọn gan ló ṣẹ̀.