Grace Olutọla: Lílo ọwọ́ òsì máa ń mú kí èèyàn tayọ láyé

Grace Olutọla: Lílo ọwọ́ òsì máa ń mú kí èèyàn tayọ láyé

Igbagbọ Yoruba ni pe lilo ọwọ osi jẹ ohun ẹgbin, iwa ibajẹ ati okunfa isẹlẹ buruku.

Amọ obinrin kan to n lo ọwọ osi, Grace Adunwọle Olutọla, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, tako iha Yooba yii si awọn eeyan to n lo ọwọ osi.

Adetọla ni, ko si iyatọ ninu kii eeyan lo ọwọ osi tabi ọtun, bẹẹ ni ko si ohun ti ọlọwọ ọtun n se, ti ọlọwọ osi ko lee se.

O tun kede pe ọwọ osi ni oun maa n fi tamba lẹyin igbọnsẹ, ti ọwọ osi lilo si maa n mu ki eeyan tayọ nile aye.

Bakan naa ni ọkọ rẹ, tun ti lẹyin pe, ọwọ osi ti iyawo oun n lo, lo mu ki oun nifẹ rẹ, to si jẹ ko rẹwa sii ni oju oun.

O fi kun pe lilo ọwọ osi maa n mu ki ọpọlọ ji pepe sii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: