Ọbasanjọ tako ìnáwó Ààrẹ Buhari fún ìpèsè inà ọba

Àkọlé fídíò,

Ọbasanjọ tako ìnáwó Ààrẹ Buhari fún ìpèsè inà ọba

Awuyewuye kò tí ì tán lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe bílíọ́nù mẹ́rìndínlógún Naira tó n fa àríyànjiyàn láàrin Ààrẹ Muhammadu Buhari àti Oluṣẹgun Ọbasanjọ.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyíì tí ìrú ẹ̀sùn bẹ̀ yóò jẹjáde lórí bí àwọn ìṣ'[akóso tó kọjá ṣe ná owó lórí ìná ọba, tí àwọn owó nàá kò sí mú àyípadà tó dára bá ẹ̀ka tó n pèsè ìná ní Nàìjíríà.

Àjọ tó n jàfún àkóyawọ́ lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajé ní Nàìjíríà, (SERAP), lọ́dún 2017 nínú àbọ̀ ìwádìí kan fi ẹ̀sùn kan ìṣèjọba Olusẹgun Ọbasanjọ, olóògbé Umar Yaradua, tó fi mọ́ Goodluck Jonathan, pé wọ́n ná bílíọ́nù mọ́kànlá Naira básu-bàṣù lórí iná ọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

'Ọ̀lọ́wọ́ òsì kọ́ndọ́rọ́'

Ṣùgbọ́n, Ààrẹ àná, Goodluck Jonathan nínú ìkède kan lójú òpó Facebook rẹ̀ ní kò ṣeéṣe fún òun sláti ná irú owó bẹ̀ ní ìnákúnàá nítorí wí pé òun làárẹ Nàìjíríà tó sọ ẹ̀ka iná mọ̀nàmọ́ná di ti aládàáni, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 2010, lásìkò tó se ìfilọ́lẹ̀ ètò àtúnṣe sí ẹ̀ka ìná ọba, títí di oṣù Kẹwàá, 2012, nígbà tó kéde títà àwọ̀n iléèsẹ́ tó n pèsè tó sì n pín iná. Àti pé níṣe lòún fi ìgbésẹ̀ nàá pawó wọlé fún orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Lọ́dún 2008 ni ilé ìgbìmọ̀ aṣojúsòfin ṣàpéjúwe bílíọ́nù mẹ́rìndínlógún tí ìṣàkóso Ọbasanjọ ná lórí iná ọba gẹ́gẹ́ bí ànádánù, tí wọ́n sì di ẹ̀bi ru àìsètò tó yẹ́ nínú àgbékalẹ̀ òwó ìṣúná, tó fí mọ́ àìní àfojúsùn ọjọ́ iwájú látọ̀dọ̀ àwọn iléèṣẹ́ tó yẹ.

Àkọlé àwòrán,

Ọbasanjọ ti kọkọ kọ lẹta si Buhari eleyi to di gbajugbaja kaakiri agbaye

Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó n jàfún àkóyawọ́ lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajé, (SERAP), lọ́dún 2016 késí adájọ́ àgbà ní Nàìjíríà, Onídàjọ́ Walter Onnoghen, láti yan agbẹjọ́rò tí kìí sẹ tìjọba láti ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tó jẹyọ nínú bí ìṣàkóso Oluṣẹgun Ọbasanjọ ṣe ná mílíọ́nù mẹ́rìndínlógún lórí iná ọba.

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé Ààrẹ Buhari sọ pé Ọbasanjọ ní ẹjọ́ láti jẹ́ lóri òbítíbitì owó tó ná lásìkò ìṣàkósò ọlọ́dún mẹ́jọ rẹ̀, Ọbasanjọ ti ní ẹ̀sùn nàá kò ní ẹsẹ̀ nílẹ̀, tó sì ti ní kí ìṣàkóso Buhari tẹ̀síwájú láti tanná wá ìdí òun.

Ọbasanjọ ní òun ti fèsì sí gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n ti fi kan òun lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà lórí iná ọba, tó fi mọ́ ìwé ''My Watch'' tí òun kọ. Ó ní ''nínú ìwé nàá lòun ti ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí òun sì tun ṣàfihàn àbọ̀ ìwádìí tí àjọ EFCC, àti ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin tó wádìí àwn ẹ̀sùn tí bí wọ́n ṣe ná owó bàntà-banta nàá sórí ìpèsè àti pípín ìná ọba láàrin oṣù Kẹfà, 1999 sí oṣù Karùn ún, 2007, láì so èso rere.