Ìrẹsì, Jéró, Ẹ̀gẹ́ àti Ewébẹ̀ nínú ewu kòkòrò Fall armyworm

Àwòran kokoro tuntun fall armyworm
Àkọlé àwòrán,

Ekòló oko ajokorun tuntun ti to n jẹ fall armyworm (FAW) ti wọ orílẹ̀-èdè ìwọ̀orùn

Ekòló oko ajokorun tuntun ti to n jẹ fall armyworm (FAW) ti wọ orílẹ̀-èdè ìwọ̀orùn àti àrin gbùngùn ilẹ̀ Àfíríkà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Èyí jẹ́ kòkòrò ajokorun ẹlẹ́ẹ̀kejì tó wọlé láti ilẹ̀ Àmẹ́ríkà tí wọn rí nínú ẹ̀gẹ́ lagbègbè gúúsù-ìlàorùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nínú oṣù kejìlá ọdún 2016.

Ìdídé kòkòrò tuntun yìí sí ilẹ̀ adúláwọ̀ tí dá ìpòrúùru sí ọkan àwọn àgbẹ̀ ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélógójì tí kòkòrò náà ti wọ̀, pẹ̀lú ìsòro tí yóò kojú Jéró, ìrẹsì àti ewébẹ̀.

Àwọn àgbẹ̀ ti kọ́kọ́ ri bíbẹ́ sílẹ̀ ọmọ kòkòrò tata èyí tó fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbàjẹ́ sí ara ẹ̀gẹ́ ní oko onílẹ̀ irínwó àbọ̀ saarè lẹ́bàá ìlú Ubiaja ní ìhà Gúúsù-ìlà Oòrùn Nàìjíríà ní ọdún 2016.

Láti ìgbà náà, kòkòrò yìí ti gbilẹ̀ gan tó sì ń jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ erè oko. Irú ìwòye yìí kan náà wáyé ní ọdún 2017 ní àwọn oko kọ̀ọ̀kan yíkáa agbègbè Dasso ní apá Gúúsù orílẹ̀èdè Benin Republic.

Àkọlé àwòrán,

Èyí jẹ́ kòkòrò ajokorun ẹlẹ́kejì tó wolé láti ilẹ̀ Àmẹ́ríkà

Látàrí gbogbo eléyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ̀nsì se ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí àti ìgbsẹ̀ láti kojú àwọn kòkòrò yìí nípa kíkó ọmọ àti àgbà wọn ránsẹ́ sí olú ilé isẹ́ ibùdó tó wà ní ìlú Ibadan tí wọ́n ti ń se ìwádìí nípa àwọn ǹkan ọ̀gbìn nilẹ̀ olóoru, Àbájade àyẹ̀wò sì jẹ́ kó di mímọ̀ pe òótọ́ ní àwọn kòkòrò ajokorun yìí ṣẹ́ jáde.