Ilé asòfin Ondo: Olórí di méjì láàrin ọjọ́ kan soso

Awọn asofin to n lu ara wọn

Oríṣun àwòrán, @jollofricejim

Àkọlé àwòrán,

Igba akọkọ kọ ree tawọn asofin yoo yọ ọwọ ẹsẹ si ara wọn

Awọn asofin ipinlẹ Ondo ti fi ija pẹẹta ni Ile Igbimo Asofin ipinlẹ naa, lẹyin ti awọn asofin di ibo lati yọ Igbakeji olori Ile Asofin, Iroju Ogundeji.

Awọn asofin ti wọn pade lati jiroro ni ile asofin, ki ijoko ile to bẹrẹ, ni iroyin sọ wi pe wọn bẹrẹ ija, lẹyin awuyewuye laarin ara wọn.

Iroyin sọ wi pe, ọkan lara wọn ju ẹsẹ lu igbakeji abẹnugan ti wọn yo ọ nipo naa.

Àkọlé fídíò,

'Ọ̀lọ́wọ́ òsì kọ́ndọ́rọ́'

Ni Ọjọ Aje ni wọn yo Igbakeji Agbẹnugan ile asofin kuro ni ipo rẹ nitori aawọ to wa laarin oun ati abẹnugan ile.

Wayi o, iroyin kan tun tẹ wa lọwọ pe awọn asofin Ondo tun ti dibo pada, ti wọn si da igbakeji Olori ile tẹlẹ, ti wọn yọ ni ipo, pada si ipo rẹ.