Àwọn òṣèré tíátà dágbére fún Ọmọge campus pé ò dìgbóṣe!

AWORAN AISHA ABIMBOLA
Àkọlé àwòrán,

Kò sí ẹni ti kò ni kú lọ́jọ́ kan

N'ise ní ìlú Èkó dákẹ́ rọ́rọ́ nígbà tí àwọn òṣeré tíátà pejọ láti ṣé ìrántí gbajugbaja òṣèré tíátà Yoruba, Aisha Abímbọ́lá to ku laipẹ́ yìí.

Awọn osere ori itage lọkunrin ati ni obinrin ni wọn si to ni ọwọọwọ pẹlu àbẹ́là lọwọ wọn lati se ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọmọge Campus, ó dàárọ̀ o

Òpó àwọn òṣeré ati ololufẹ oloogbe to wa nibẹ wọ aṣọ dudu ti wọn ya àwòrán Aisha si lati kẹdun oloogbe náà ti àrùn jẹjẹrẹ ọyàn pa lọjọ kẹrindinlogun osu karun-un ọdun 2018.

Àkọlé àwòrán,

Awon osere tan ọ̀pọ̀ àbẹ́là ni iranti Aisha Abimbola

Ọgba Ile iṣẹ amóhunmáwòrán LTV ni Ikẹja ni ilú Èkó si ni ẹyẹ ikẹyin naa ti bẹrẹ.

Lara awọn osere ori itage to peju sibi ẹyẹ ikẹyin naa ni Saheed Balogun ati ilumọọka ajafẹtọ ẹni nni, Okei Odumakin.

Àkọlé àwòrán,

Joe Odumakin ati Saheed Balogun wa lara awon ilumooka to pejo sibi ale iranti naa

Aisha ni ìròyìn gbalẹ̀ kan ní ààrọ̀ Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹ́rindinlogun, osu karun-un, ọ̀dun 2018 lórí ìtàkùn àgbáyé pé, ó ti mí kanlẹ̀ lẹyin àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ.

A gbọ́ pé àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn tó ń bá Aisha fínra, láti ọjọ́ díẹ̀ ló gba ẹ̀mi rẹ̀.

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀ àwọn òsèré tíátà, tí wọn jẹ́ akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ń se ìdárò iku Aisha Abimbọla

Ọ̀pọ̀ àwọn òsèré tíátà, tí wọn jẹ́ akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ń se ìdárò ikú ìlúmọ̀ọ́ká òsèrè tíátá obìnrin náà láwọn ojú òpó ìkànsíra ẹni wọn lórí ìtàkùn àgbáyé Facebook àti Instagram.

Aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́bọ, ọjọ kẹ́tadinlogun osu karun-un ni wọn sìnkú olóògbé Aisha Abimbọla ní orílẹ̀èdè Canada.