Ileesẹ ọmọogun Nàìjìríà: A ò fipá bá ẹnikẹ́ni lò ní ìpàgọ́

Aworan awon ọmọogun
Àkọlé àwòrán,

Sùgbọn agbẹnusọ fún àjọ ọmọogun sọ pé irọ́ pátápátá ni ọrọ náà pé àwọn ń fi tipátipá báwọn aṣàtìpó lájọṣepọ̀

Ìròyìn tuntun tún jáde pé àwọn ọmọogun orílẹ̀-èdè Nàìjìríà ń ṣe àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn abilékọ to sá fún ìkọlù Boko Haram báṣubàṣu.

Àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ Amnesty International ni àwọn aṣàtìpó ń ṣe èyí ní àwọn aṣatipo ń fi ṣe pàṣípààrọ̀ pèlú ounjẹ̀ àti àti àwọn ohun èlò mííràn tókù ni ibùdó ní.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn tó tẹ BBC Yorùbá lọ́wọ́ sọ pé ẹ̀rí Amnesty International dá lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò ti wọn ṣe fún àwọn àádọ́talénígba eniyan ní budo àwọn tó sá fun ìkolù Boko Haram tí wọn ṣe láàárin ọdún 2016 sí 2018.

Wọn ní àwọn ọmọogun máa ń fipá bá àwọn obìnrin sùn ti wọn sì ń fiwọn fọ́kọ pẹ̀lúu túlàsì, Amnesty ni wọn rí èyí ṣe ní ìdápadà fún oúnjẹ àti ààbò.

Obìnrin mẹ́sà-án ní wọn ti fi tipá bálòpọ tí wọn sì fi ìyàwó àwọn Boko Haram séwọ̀n lọ́nà àìtọ́, pẹ̀lú ẹ̀rí pé àwọn márùn-ún àti ọmó wẹ́wẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n ló ti kú.

Sùgbọn agbẹnusọ fún àjọ ọmọogun sọ pé irọ́ pátápátá ni ọrọ náà pé àwọn ń fi tipátipá báwọn aṣatipo lájọṣepọ̀ ni ipagọ.