Kin lo de ti ọ̀rọ̀ ajínigbé ni Kaduna ń peléke síi?

Awon agbofinro
Àkọlé àwòrán,

T'obìnrin àti t'ọmọde ni wọn ń jigbe kaakiri bayii

Ọrọ ti di ojú ni alákàn fi ń ṣọ́rí nipinlẹ Kaduna báyìí lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Ọpọ̀ ìgbà ni àwọn oníṣẹ́ ibi ti foju àwọn ènìyàn Brinin Gwari nipinlẹ Kaduna ri èèmọ̀ láti ìgbà díẹ̀ sẹyin.

Lẹyin ti wọn pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ laípẹ nigbe wọn de etí ijọba apapọ Nàìjíríà, ti Aare Buhari si ni ki ikọ̀ àwọn ọmọ ogun ati agbofinro kan kó lọ sibẹ.

Awọn awakọ ni agbegbe Birnin Gwari lo tun kigbe pe àwọn ajinigbe ji àwọn èrò to to marundinlaadọta to n lọ lati àríwá si gúúsù Nàìjíríà gbé.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ajinigbe ń ṣọṣẹ́ ni Birnin Gwari

Wọn ni àwọn agbebọn fipa ń da ọkọ duro ti wọn si n ko èrò wọ inu igbó lọ.

Ọpọ ẹbí lo ń wa owó ìtanràn bayii bii ti oloselu Zamfara ti àwọn ọlọpaa ṣì ń wa iyawo rẹ ati ọmọ mẹfa ti àwọn ajinigbe ji bayii.

Awon to n gbe agbegbe yii ni ijọba ko tii mu ìlérí to ṣe fún wọn lori ìpèsè ààbò ṣẹ́ rara

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: