Ebola: Àwọn aláìsàn mẹ́ta sá kúrò níléwòsàn ní DR Congo

Àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera
Àkọlé àwòrán,

Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ènìyàn tí àìsàn Ebola pa ní ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn Afrika láàrin 2014 sí 2016

Àwọn aláìsàn Ebola mẹ́ta sá kúrò ní ibùdó ìtọ́jú gba ṣọ́ọ̀sì lọ ní orílẹ̀-èdè Democratic Republic of Congo.

Àjọ tó n mójútó ètò ìlera ní àgbáyé, WHO, ní wọ́n fi ilé ìwòsàn ti wọn ti n gba itọju sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ní àwọn gbọdọ̀ gbé wọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì.

Méjì nínú àwọn aláìsàn nàá padà jẹ́ Ọlọ́run nípè, tí ẹnì kẹta padà sí ibùdó ìtọ́jú nàá ní ìlú Mbandaka.

Èyí ti wá mú kí ẹ̀rù ma ba àwọn aláṣẹ pé ó ṣeéṣe kí àìsàn nàá tàn yíká ìlú Mbandaka. Àti pé sísá tí àwọn èèyàn naa sá nílé ìwòsàn jẹ́ ìpèníjà ńlá fún àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó n là kàkà láti fòpin sí ìtànkálẹ̀ Ebola ní orílẹ̀-èdè DR Congo.

Àkọlé àwòrán,

Ìgbà kẹsàn án nìyí tí àìsàn Ebola yóò bú jáde ní orílẹ̀èdè DR Congo.

Báwo ni wọ́n ṣe rí ààyè kúrò nílé ìwòsàn?

WHO ní àwọn ẹbí àwọn aláìsàn nà wá sí ibùdó ìtọ́jú ọ̀hún, tó jẹ́ ti àjọ aláànú, Medecins Sans Frontieres, tí wọ́n sì ní kí wọ́n yọ̀ǹda àwọn ènìyàn wọn fún wọn, kí àwọn le gbé wọn lọ fún ètò àdúrà, tí wọ́n sì gbé wọn lọ lórí ọkàdà.

Ilé ìwòsàn MSF ní gbogbo akitiyan àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn nà láti káwọn lọ́wọ́ kò, ló já sí pàbó.

Ní báyìí, wọ́n tí n ṣọ́ àwọn ẹbí àwọn aláìsàn mẹ́tẹ̀ẹ́ta, tí díẹ̀ lára wọn sì ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí Ebola.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àjọ WHO ní ''ìtànkálẹ̀ àìsàn náà ní agbára láti pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.''

Ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kárùn, ni àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn ará ìlú ní abẹ́rẹ́ àjẹsára, láti dá ìtànkálẹ̀ àìsàn náà dúró.

Ìgbà kẹsàn-án nìyí tí àìsàn Ebola yóò bú jáde ní orílẹ̀-èdè DR Congo.