Keyamo: Cocaine tí ò ń fà ní o da orí rẹ rú

Obasanjo àti Buhari
Àkọlé àwòrán,

Bi ó tilẹ̀ jé pé Ààrẹ Muhammadu Buhari kò dárúkọ Ààrẹ kankan nínú ọrọ rẹ̀

Lórí awuyewuye tó ń tàn ká lórí ẹ̀sùn tí Ààrẹ Muhammadu Buhari fí kàn ààrẹ àná, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ

Esun naa kò ṣẹyin owó bilìọ̀nù dọ́là mẹrindinlogun to yẹ fún iṣẹ́ mọ̀namọ́na lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò ní ipa lo tí dì ohun ti à ń gbà bí ẹní gba igbá ọtí láàárín àwọn èèkàn orílẹ̀-èdè yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

"Ẹ jẹ́ kí Buhari lọ jókòó"

Ààrẹ Muhammadu Buhari kò dárúkọ Ààrẹ kankan, sùgbọn ní báyìí àwọn olólùfẹ́ Ààrẹ Buhari àti Ààrẹ Ọbasanjọ tí bẹ̀rẹ̀ sí ní tahùn sí ara wọn bayii.

Fún àpẹrẹ, Femi Fani Kayode ni aṣiṣe nla ni Ọbasanjọ ṣe ti kò sọ Buhari sẹwọn lori kiko owo PTF jẹ. O ni ko yẹ ki Ọbasanjọ gba ẹbẹ Buhari nigba to ń sunkun bi ìkókó pe

Bẹẹ, Dada kò le ja ni ọrọ Buhari, o ni aburo to gboju nitori pe Festus Keyamo naa fun Femi Fani-kayode lesi pe, aṣiṣe Ọbasanjọ ni yiyan àwọn to n mu oogun oloro sipo olori bii Fani-kayode

Àjọ tó n jà fún àkóyawọ́ lẹ́ka ètò ọrọ̀ Ajé ní Nàìjíríà, (SERAP), lọ́dún 2017 nínú àbọ̀ ìwádìí kan fi ẹ̀sùn kan ìṣèjọba Olusẹgun Ọbasanjọ, olóògbé Umar Yaradua, tó fi mọ́ Goodluck Jonathan, pé wọ́n ná bílíọ́nù mọ́kànlá Naira básu-bàṣù lórí ọrọ iná ọba.