Ọmọge Campus jẹ́ ẹni tó kó ẹbí mọ́ra

Àwọn òṣèré tíátà lédè Yorùbá ní orílẹ̀èdè Nàíjíríà ti sètò ẹ̀yẹ ìkẹyìn láti dágbére fún Aisha Abimbọla, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ọmọge Campus pé ò dìgbóṣe.

Níbi ẹ̀yẹ ìkẹyìn náà ni wọ́n ti kọrin ki Ọmọge Campus, tí wọ́n sì tan àbẹ́là láti dárò rẹ̀.

Nígbà tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Musa Ibrahim tó jẹ́ àbúrò Aisha sàlàyé pé ológbèé náà jẹ́ ẹni tó kó ẹbí mọ́ra, tí gbogbo ẹbí sì fẹ́ràn púpọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: