Àwọn òsèré: Ìgbé ayé Ọmọge Campus jẹ́ ẹ̀kọ́ fún wa

Ìkẹ̀jà pa lọ́lọ́ lálẹ́ ọjọ́rú nígbàtí àwọn òsèré tíátà tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ pẹ̀lú àbẹ́là lọ́wọ́ wọn èyí tí wọn fi ń se ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Aisha Abimbọla.

Àwọn gbajúmọ̀ òsèré bíi Saheed Balogun, Sọla Kosọkọ, Sunkanmi Ọmọbọlanle ati ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni, Okei Odumakin ni wọ́n se ìdárò olóògbé náà.

Wọ́n fi kún-un pé Obìnrin dúndùn abi ìwà dúndùn ni Aisha.

Nígbà tí wọn ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, àwọn òsèré náà ní, ẹni tó ní ìpinnu ọkàn ni Aisha, oun tó bá ní òun yóò se, ni yóò se.Wọ́n wa rọ gbogbo èèyàn láti fi okun àti ìwà akin Ọmọge Campus náà se àwòkọ́se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: