Trump: ojú agan tí Kim gbé ni mo se wọ́gilé ìpàdé wa

Aarẹ Trump ati Kim Jong-un Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Trump kesi Kim lati pe oun lori ẹrọ ayelujara to ba ti yi ọkan rẹ pada

Aarẹ Ilẹ Amẹrika, Donlad Trump ti fagile ipade po pẹlu Aarẹ Ilẹ North- Korea, Kim Jong-Un.

Aarẹ Trump wi pe, oun gbe igbesẹ naa nitori oju agan ati ọrọ ibinu ti o tẹnu aarẹ ilẹ North Korea naa jade ninu atẹjade rẹ.

Trump ninu atẹjade rẹ fikun wi pe, oun ti o tọ ni lati takete si ipade naa nitori North Korea sọ wi pe, oun ni ohun ija asekupani ọlọgọọrọ nuclear.

Amọ, aarẹ ilẹ Amẹrika naa ni, ohun ija ilẹ Amẹrika ju ti North Korea lọ, sugbọn awọn lero wi pe, awọn ko ni nilo rẹ rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọge Campus jẹ́ ẹni tó kó ẹbí mọ́ra

Nipari atẹjade naa, Aarẹ Trump kesi Kim lati pe oun lori ẹrọ ayelujara oun, to ba ti yi ọkan rẹ pada.

Ti a ko ba gbagbe, ọkan lara awọn asoju fun ilẹ North-Korea, Choe Son-hui ni ọrọ asan ni ọrọ Aarẹ Trump to wi pe North Korea yoo dabi Libya.