Kí ló n dá iṣẹ dúró lórí afárá ọya kejì?

Aworan afárá ọdọ ọya keji

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Wọn kọkọ bẹrẹ iṣẹ ipile afárá náà labẹ ìjọba Goodluck Jonathan lọdun 2014

Ẹnikẹ́ni to bá ti ni anfààní ati rin irinajo kọja lorí afárá odo ọya to so Onitsha ni ila oòrùn gúsù àti Asaba ni apá gúúsù yóò mọ ìnira ti ojú àwọn arinrin-ajo máà n rí l'agbegbe òun.

Mímú idẹkùn bá ará ìlú wá lara idi ti awọn ijọba to ti kojá sẹyìn ni Naijiria fi ni, awon yóò kọ afárá keji ti yóò gbà orí odo ọya kọjá.

Ala náà kò ti di mimuṣe bi a ti ṣe n ko ìròyìn yìí jọ, ṣugbọn ó yẹ ká mọ nkàn díẹ̀ nípa afárá náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdún tí wọn kọ afárá odo ọya àkọkọ

Ọdún kàn ní wọn fí ko afárá odo ọya àkọkọ láàrin 1964-1965.

Olori ijoba nigba naa, Tafawa lo ṣé ìfilọ́lẹ̀ rẹ lọdun 1966.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ìṣe ìpìlẹ afárá náà nìkàn ní wọn ṣì ṣé

A gbọ pe mílíọ̀nù mẹfa pọ́un o le diẹ, ni wón fún agbàṣẹ́se tó kọ afárá ọhun nigba náà.

Nígbà ogun abẹ́lé Nàìjíríà to waye laarin ọdun 1967-1970, wọn já apa kan afárá náà.

Ọpọ ìjọba ti ṣe Ìlérí oríṣiríṣi lórí afárá náà

Ọpọ ìjọba àná lorílè-èdè Naijirià lo ti tẹpele mo pàtàkì kíkọ afárá keji, ti yóò gbà orí odò ọya kọjá lati mú adinku ba sùnkẹrẹ fakẹrẹ ti o pọ lórí afárá àkọkọ.

L'ọdun 2007, Aare àná Olusẹgun Obasanjo ṣe ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ lórí afárá náà, eyi t'owo rẹ to biliọnu mejidinlogoji naira le díè.

Ọdún mẹrin ni wọn ní àwọn yóò fi parí afárá náà.

Eto idokowo pọ láàrin ìjọba àti aladani sí ni won láwọn yóò fí ṣe e.

Jonathan náà ṣe ìfilọ́lẹ̀ ti

Nígbà ti ìdìbò ọdún 2015 n sunmọ, ìjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan kéde pé oun yóò bẹrẹ iṣẹ lórí afárá keji.

Tayọ ti ìdùnnú láwọn ará agbègbè náà fi gba ìròyìn náà.

Biliọnu metadinlọgofa naira ni wọn láwọn yóò fi kọ afárá náà àti ojú ọnà tó so pọ.

Wọn bẹrẹ iṣẹ níbi afárá náà ti wọn sì bẹrẹ sí ní rí opo ti yóò di afárá náà mú.

Ọdún mẹrin láwọn náà láwọn yóò fi kọ.

Ìjọba Jonathan lo kọkọ san owó fún ile iṣẹ Julius Berger, láti bẹrẹ iṣẹ ipile afárá náà.

Owó tí wọn sàn ló jẹ kí wọn lè ṣíṣe lórí ipele kinni, ìkejì àti lára ìpele kẹta iṣẹ ipile afárá náà.

Ìbí ti wọn bá iṣẹ dé ní ìjọba Buhari tí gbà a.

Lábẹ́ ijoba Buhari nibo ní iṣẹ dé?

Àlàyé pàtàkì àkọkọ nipa afara odo ọya ní pé, àjọṣepọ pẹlú aladani ni awọn ijoba orisirisi n gbèrò láti lo fi kọ afárá elèkejì yii.

Labẹ ijoba Buhari, awọn naa kò ti f'owo bọ ìwé lórí iye owó pato tí wọn yóò fi parí gbogbo iṣẹ pátápátá lórí afárá keji.

Oríṣun àwòrán, @Laurestar

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti fẹ mú ọrọ̀ òṣèlú wọnú kikọ afárá náà

Mínísítà fún ètò òhun amusagbara, iṣẹ ode ati ilegbe, Ọgbẹni Babatunde Fashola, ko ye maa tẹnumọ ifarajin ìjọba ode oni láti kọ afárá náà.

Lai pé yí ni awuyewuye wáyé lórí dédé ìbí ti won ba iṣẹ dé lórí afárá náà.

Nigba to n ṣe àyẹwò sí afárá náà, Fashola ni iṣẹ ibẹrẹ pẹpẹ riri òpó tí yóò mú afara náà dúró ni awọn sí n ṣé lọwọ, ti ọ sí ti dé idà àádọta nínú ìdá ọgọrun dédé iṣẹ naa.