Olóri aṣòfin Ekiti: Igbákejì mi ń hùwà kòtọ́ la se yọ́ nípò

Aworan ile asofin Ekiti Image copyright Ekiti State Government
Àkọlé àwòrán Ile asofin Ekiti nigba ti Gomina Fayose gbe aba isuna odun 2017 wa si iwaju won

Yorùbá ní ohun tó ń se Lébánjé kò se ọmọ rẹ̀, Lébánjé ń sunkú owó, ọmọ rẹ̀ ń sunkún ọkọ.

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Èkìtì nítorí lọ́jọ́ ti Gómìnà Ayodele Fayose, tií se gómìnà ìpínlẹ̀ náà n ṣé ìfilọ́lẹ̀ ilé ẹjọ gíga ìpínlè Èkìtì, ni àwọn aṣòfin gbimọrán láti yọ igbákejì olórí ilé àti akojanu ilé asòfin ìpínlẹ̀ náà.

Ọgbẹni Adesegun Adewumi àti Ọgbẹni Akinniyi Sunday ni won yọ bi ẹni yọ jìgá ní ọjọ́rú ní ipò ìkọ̀ọ̀kan kóówá wọn.

Kété ní àwọn ọmọ ile sí ti yan Ọgbẹni Onigiobi Olawale, láti rọpo Akinniyi gẹgẹ bí akojanu ilé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn tó tẹwa lọwọ sọ pé, olórí ilé, Akinyẹle Olátúnjí fẹ̀sùn kan igbákejì rẹ̀ pé o ń kópa nínú àwọn ìwà kan tó lè ṣe àkóbá fún ìdúró-sìnsìn ilé.

Àwọn asòfin méjìdínlógún ni wọ́n lò tọwọ bọ ìwé iyọni nípò òhun, ni ìbámu pẹlú òfin orílèèdè Nàìjíríà.

Àmọ́ Gómìnà Ayodele Fayose kò ti sọrọ kánkan lórí ìṣẹlẹ náà, yálà lójú òpó Twitter rẹ tàbí láti ẹnu àwọn oluranlọwọ rẹ.

Bẹ́ẹ̀ bá sì gbàgbé, wákàtí mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn ni irúfẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo, níbití wọn ti yọ igbákejì ilé asòfin ìpínlẹ̀ náà, kí wọn tó dáa padà ní ọjọ́ kejì sí ipò rẹ̀.