Kwesi gbòmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò

Aworan kwesi Nyantekyi,
Àkọlé àwòrán,

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ghana yíì tí kóbá ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù ibẹ̀ láti rí onígbọ̀wọ̀ fún eré bọ́ọ̀lú

Wọ́n ti kìlọ̀ ìṣọ́ra fún ààrẹ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Ghana àti igbákejì àjọ CAF, Kwesi Nyantekyi

Bákan náà ní wọn ti gba ìdúró rẹ̀ lẹ́yìn tí wọn ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò fún un tán lóri lílo ọ̀nà àlùmọ̀kọrọ́yí lu jìbìtì.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn ọlọ́pàá sọ fún ikọ̀ ìròyìn BBC pé wọn ó pèé lẹ́jọ́ ní ìlànà òfín ní kété tí ìwádìí bá ti parí.

Nyantekyi ní wọn kámọ́ nínú fọnrán kan tó tí ń ṣe ìpàdé ìdákankọ́ olówó ńlá kan lórúkọ ààrẹ orílẹ̀-èdè Ghana, Nana Akufo-Addo, àti igbákejì rẹ̀.

Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nùwò bíi wákàtí márùn-ún pẹlu ọ̀ga ọlọ́pàá, tí wọn sì yẹ ẹ̀rọ kọ̀mpútà àti ilé rẹ̀ wò, kò sí ohun kan tó ṣe àkóbá fún.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ghana yíì tí koba ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù ibẹ̀ láti rí onígbọ̀wọ̀ fún eré bọ́ọ̀lú ní orílẹ̀-èdè náà.